Jide Alabi
Ko ti i sẹni to mọ ohun to fa ijamba ina kan to tun ṣẹlẹ nibi biriiji Ọtẹdọla, nitosi Sẹkiteriati Alausa. Niṣe ni ina n sọ lalaala, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ.
Iṣẹlẹ ina yii ti fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ ni gbogbo agbegbe naa.
Ibẹrubojo iṣẹlẹ yii lo mu ki ọpọ mọto maa ṣẹri pada, ti awọn mi-in si sa jade ninu mọto, ti wọn n fẹsẹ rin lọ sibi ti wọn ro pe ko sewu.
Gbogbo awọn to wa nibi iṣẹlẹ yii ni wọn n pariwo pe o yẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si ọna naa pẹlu bi ijamba ina ṣe maa n fi gbogbo igba ṣẹlẹ nibẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ko ti i pẹ rara ti ijamba ina kan ṣẹlẹ nibẹ.