Ẹfun abeedi! Benedict sa ọrẹ rẹ pa n’Ipele o tun ge ori rẹ pamọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ kootu Majisreeti to wa lagbegbe Oke-Ẹda,  l’Akurẹ, ti ni ki wọn si lọọ fi ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Owalum Benedict Ochin, pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun pe o gbe ori ọrẹ rẹ, Ekon, pamọ lẹyin to ti kọkọ ṣa a ladaa pa mọ inu igbo, nitosi Ipele, nijọba ibilẹ Ọwọ.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun ta a wa yii.

Ninu alaye ti olujẹjọ ọhun ṣe lasiko to n fara han nile-ẹjọ, o ni lati ilu Calabar loun ti wa, ati pe ọrẹ timọtimọ loun ati oloogbe.

O ni ibi ti oun ti n wa iṣẹ toun fẹẹ maa ṣe  loun ti pade Blessing Opor atawọn meji mi-in ti awọn mẹrẹẹrin si jọ n ṣiṣẹ lebira ninu oko igbo kan to wa nitosi Ipele.

Ọrọ ewe kan ti Ekon fi sinu ọbẹ ti wọn se lọjọ iṣẹlẹ naa lo ni o da wahala silẹ laarin awọn mejeeji, nitori pe ko si igba ti oun jẹ kinni ọhun ti ki i pa oun lara.

Benedict ni ibi tawọn ti n fi ada ṣa ara awọn ni ọrẹ oun ti fara pa to si gba ibẹ ku.

Lẹyin eyi lo tun fada ge ori rẹ, eyi to lọọ ri mọlẹ nibi kan, ki asiri rẹ ma baa tu pe o ti paayan.

Ẹsun ipaniyan ati igbiyanju lati ṣeku pa ẹnikan ti wọn n pe ni Blessing Opor ni wọn fi kan an n’ile-ẹjọ.

Awọn ẹsun yii ni Agbefọba, Uloh Goodluck, ni o lodi labẹ ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ N. T. Aladejana, ni ki olujẹjọ ọhun ṣi lọọ maa ṣere rẹ ninu ọgba ẹwọn titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

Ọjọ kọkanlelọgbọn, osu kin-in-ni, ọdun 2021, lo sun igbẹjọ mi-in si.

 

Leave a Reply