Faith Adebọla, Eko
Ijamba ọkọ ayọkẹlẹ to ṣẹlẹ ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti mu ẹmi eeyan mẹta lọ lẹyẹ-o-sọka nibudokọ Cement, lagbegbe Iyana Dọpẹmu, bẹẹ lawọn mẹta mi-in ṣi wa ni bi-yoo-ku bi-yoo-ye.
Ọkọ ayọkẹlẹ SUV kan la gbọ pe o sare asapajude, to si lọọ sọri mọ tirela to n lọ niwaju ẹ lọna marosẹ Abẹokuta si Eko, ti eyi si ti fa sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ rẹpẹtẹ loju ọna naa, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ oju popo ti n ṣiṣẹ gfidigidi lati mu ki lilọ bibọ ọkọ sunwọn si i.
Alukoro fun ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko (LASTMA), Ọgbẹni Olumide Filade, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o sọ pe awọn ti ko awọn oloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa nitosi, wọn si ti ko awọn to fara gbọgbẹ lọ sọsibitu pẹlu.