Ijamba ọkọ fẹmi eeyan meji ṣofo, mẹtala fara pa yannayanna

Adewale Adeoye

Eeyan meji lara awọn to ni ijamba ọkọ lagbegbe Ajebọ, ni J4, loju ọna marosẹ Sagamu si Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti jẹ Ọlọrun nipe bayii, nigba tawọn mẹtala ti wọn fara pa yannayanna ninu ijamba naa wa nileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Hope Hospital, to wa lagbegbe naa, ti wọn n gba itọju lọwọ.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ijamba ọkọ naa waye ni nnkan bii aago mejila ọsan. Mọto akero Toyota Hiace kan ti nọmba rẹ jẹ ‘GUE 59ZY’, ati mọto tirela kan ti nọmba rẹ jẹ ‘BGT 94 LG’, ni wọn jọ fori sọ ara wọn ti ijamba naa fi waye.

Alukoro ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC), ẹka tipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpem to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun yii, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, sọ pe ere asapajude ti ọkan lara awọn dẹrẹba naa n sa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘Ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Ero mẹẹẹdogun lo wa ninu ọkọ derẹba yii, ọkunrin mẹwaa, obinrin marun-un, ere asapajude ti dẹrẹba ọkọ akero ọhun n sa lọjọ naa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun, ṣe lo lọọ kọ lu tirela kan to bajẹ sẹgbẹẹ ọna, ti awọn meji si ku loju-ẹsẹ ninu awọn ero ọhun. Awọn mẹtala ni wọn fara pa yannayanna, ṣugbọn wọn n gba itọju lọwọ nileewosan alaadani kan ti wọn n pe ni ‘Hope Hospital’,  to wa lagbegbe naa.

Alukoro waa gba awọn dẹrẹba ọkọ akero lamọran pe ki wọn yee sare asapajude lasiko yii, ki ijamba ọkọ le dinku laarin ilu.

Leave a Reply