Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan meji loju ọna lleṣa si Akurẹ

Florence Babaṣọla

 

O kere tan, eeyan meji lo gbẹmii mi nigba ti awọn mẹta mi-in fara pa nibi ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ laago mẹwaa alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, lorita Ẹrinmọ, lopopona Ileṣa si Akurẹ.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ ẹṣọ oju popo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣe sọ, ere asapajude ati aibọwọ fun ofin irinna lo fa iṣẹlẹ ijamba naa.

O ni mọto akoyọyọ DAF alawọ eeru to ni nọmba XP 817 EPE ati Toyota Hiace Bus to ni nọmba DKA 597 BQ ni wọn fori sọ ara wọn.

Ọkunrin mẹfa lo wa ninu mọto mejeeji, loju-ẹsẹ si lawọn meji ti ku, nigba ti awọn mẹta fara pa yanna-yanna.

O sọ siwaju pe wọn ti gbe oku kan ti wọn ri yọ lọ sile-igbokuu-si ti ileewosan Wesley Guild Hospital, nigba ti wọn n wa ọna lati yọ oku keji jade.

 

Leave a Reply