Ijamba ọkọ tun fọpọ ẹmi eeyan ṣofo l’Akungba-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan bii marun-un ni wọn pade iku ojiji, nigba tọpọ tun fara pa ninu ijamba ọkọ mi-in to waye niluu Akungba-Akoko lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọkọ ajagbe kan to kun fọfọ fun ẹru, eyi to n bọ lati ọna ilu Ọwọ lo deedee pada sẹyin lasiko to n gun ori oke Okerigbo, nitosi Fasiti Adekunle Ajasin, to si ṣe bẹẹ ṣubu sinu koto kan to wa lagbegbe naa.

Ọkọ ọhun ti subu tan kawọn oluworan too ṣakiyesi pe awọn eeyan wa labẹ rẹ.

Ko pẹ rara tawọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ oju popo fi de si ibi  ijamba ọkọ naa ti wọn si ko oku awọn to ba iṣẹlẹ ọhun rin lọ si mọsuari.

Ọkan ninu awọn agba Musulumi lagbegbe Akoko, Alaaji Ibrahim Kilani, ni o digba ti ijọba ipinlẹ Ondo ba ṣe atunṣe ọna marosẹ to gba ori Okerigbo kọja ki adinku too de ba ijamba ọkọ to saaba maa n waye lagbegbe naa.

Leave a Reply