Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan meji ni wọn tun padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ to waye lagbegbe Ọkọrun, niluu Ikarẹ Akoko, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a wa yii.
Ijamba ọkọ yii waye nibi kan naa ti ọkọ ajagbe ti tẹ awọn mẹjọ pa, ti ọgọọrọ awọn eeyan si tun fara pa lọjo diẹ sẹyin.
ALAROYE gbọ pe awakọ ayọkẹlẹ Nissan Primera kan ni lo padanu ijanu ọkọ rẹ lasiko to n sọkalẹ lori oke nla to wa lagbegbe naa, to si lọọ kọlu awọn meji to wa lori ọkada Bajaj ati ẹni kan to n rin lọ lẹgb€ẹ ọna.
Loju ẹsẹ lawọn meji ti ku, ti ẹni kẹta wọn si wa nibi to ti n gba itọju lọwọ nileewosan Ijọba to wa n’Ikarẹ Akoko.
Wọn ni awakọ yii kọkọ yọ ori jade lẹyin to ṣakiyesi pe ijanu ọkọ oun ko ṣiṣẹ mọ, to si n ke tantan kawọn eeyan le ya kuro lọna, ṣugbọn ko ṣẹni to mọ itumọ ohun to n sọ titi ti ọkọ yii fi mu ẹni meji balẹ, ko too pada duro.
Oku awọn eeyan ọhun ṣi wa ni mọsuari ileewosan ijọba niluu Ikarẹ lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.