Ijanba ina ba dukia jẹ l’Ebute-mẹta

Aderounmu Kazeem
Ninu ibanujẹ nla lawọn olugbe atawọn to ni ṣọọbu laduugbo Kano Street, l’Ebute-Mẹta, Eko, wa bayii lori ijanba ina to ṣẹlẹ to si ba gbogbo dukia wọn jẹ.
Lọwọ irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ni wọn sọ pe ina ọhun bẹrẹ, ina ijọba ti waya ẹ kan ara wọn ni wọn sọ pe o fa a, ki wọn si too ṣe ohunkohun si i, ina nla ti sọ, bẹẹ lọpọ dukia atawọn ọja pako lagbegbe naa si ṣe bẹẹ jona guruguru.
ALAROYE gbọ pe ohun to tubọ mu ina ọhun fẹju ni bi gaasi, iyẹn afẹfẹ idana tawọn eeyan kan fi n dana lagbegbe ọhun naa ṣe dun gbamu, to si mu iṣelẹ naa fẹju si i.
Ohun tawọn to ni sọọbu lagbegbe naa n bẹbẹ fun bayii ni bi ijọba ko ṣe ni gba agbegbe naa lọwọ wọn, ti wọn yoo fun wọn lanfaani lati tun ibẹ kọ pada, pẹlu owo iranwọ lati ọdọ ijọba, ki iṣoro ina yii ma maa da nnkan ru fun wọn ju bayii lọ.
Ileeṣẹ panapana to wa ni Iganmu ati Ilupeju l’Ekoo la gbọ pe o waa ba wọn pana ọhun lẹyin to ti jo fun bii wakati mẹfa.
Adele fun ileeṣẹ panapana l’Ekoo, Arabinrin Margaret Adeṣẹyẹ, sọ pe ninu ira lawọn eeyan ọhun kọ ile wọn si, bẹẹ lo ṣoro fun ileeṣẹ panapana lati tete ri ibẹ wọ, ṣugbọn awọn ileeṣẹ panapana to wa lati Ilupeju ati Iganmu gbiyanju daadaa, wọn si pada ri ina ọhun pa patapata ni nnkan bii aago mjeila abọ oru.
Pupọ ninu awọn ti wọn n taja nibẹ ti ọja wọn ba iṣẹlẹ ina ọhun lọ ni wọn n bẹ ijoba bayii ko ṣeto iranwọ owo, ki iṣẹlẹ ọhun ma baa sọ wọn di ẹdun arinlẹ

Leave a Reply