Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti di alainile lori latari iji nla kan to ja lasiko ojo to rọ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii.
Lara awọn agbegbe ti iji ọhun ti ṣọṣẹ ni: Òkè-Idẹra, Adegoju, Akinmarin, Arowojaye, Alaafiatayọ, Oluwalomọṣe, Awolọpẹ, Wẹmi Akinṣọla atawọn adugbo mi-in.
Nigba ti ALAROYE ṣabẹwo sawọn adugbo naa laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, awọn adugbo ti iji ọhun ti lagbara ju lọ ni Wẹmi Akinṣọla, Akinmarin ati Adegoju.
Ọpọ awọn ile, ṣọọbu, ile-iwe atawọn ṣọọsi to wa laduugbo mẹtẹẹta ni wọn fara gba ninu iṣẹlẹ naa. Ṣe lo kan awọn orule ile atawọn ṣọọbu kan lọ patapata, nigba to fi awọn mi-in silẹ laabọ.
Ọpọlọpọ opo ina to wa lawọn agbegbe wọnyi lo ti wo lulẹ, ti awọn waya ori wọn si fọn kaakiri oju ọna, leyii to fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ awọn ọkọ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ati aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Ọkan ninu awọn olugbe agbegbe naa to ba wa sọrọ, Pasitọ Timothy Ọlanrewaju, ni ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ku isẹju diẹ lojo ọhun bẹrẹ lalẹ ọjọ Aje, ko si rọ ju bii iṣẹju mẹwaa pere lọ to fi da.
Ojiṣẹ Ọlọrun ọhun ni iji jija lo kọkọ ṣaaju, ki ojo too bẹrẹ si i rọ. O ni gbogbo ile to wa laduugbo Wẹmi Akinṣọla, nibi ti ijọ to n bojuto, iyẹn Christ Apostolic Church, Ọlọrunṣogo, wa ni iji naa fọwọ ba.
Ọlanrewaju ni bo tilẹ jẹ pe apa kan orule ṣọọsi naa ni iji ọhun ka lọ, síbẹ̀ ibẹ ni pupọ awọn eeyan adugbo naa pada waa sapamọ si titi ti ilẹ fi mọ nitori ile tiwọn naa fara gba ninu ijamba ọhun.
Ẹlomi-in to tun ba wa sọrọ, Ọgbẹni Akinkuoliẹ Ayọọla, ni gbogbo orule ile alaja kan ti oun n gbe atawọn ṣọọbu to wa layiika rẹ ni iji ọhun ka lọ.
O bẹ ijọba lati dide iranlọwọ fun un, nitori ọpọ dukia olowo iyebiye lo ṣegbe latari ojo nla to rọ lẹyin iji naa.
Igbakeji alaga ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, Ọnarebu Jimi, ni ti ṣabẹwo si awọn agbegbe ti wọn fara gba ninu iṣẹlẹ naa.