Iji lile ṣọṣẹ ni Kwara, ọpọ araalu di alainile lori

Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti di alainile lori latari iji nla kan to ja lasiko ojo to rọ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Lara awọn agbegbe ti iji ọhun ti ṣọṣẹ ni Ìgbómìnà, nijọba ibilẹ Ọ̀yun, atawọn adugbo mi-in.

Ọpọ awọn ile, ṣọọbu, to wa laduugbo ọhun ni wọn fara gba ninu iṣẹlẹ naa. Ṣe lo ka awọn orule ile atawọn ṣọọbu kan lọ patapata, nigba to fi awọn mi-in silẹ laabọ.

Ọpọlọpọ opo ina to wa lawọn agbegbe wọnyi lo ti wo lulẹ, ti awọn waya ori wọn si fọn kaakiri oju ọna lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii.

Aarẹ ẹgbẹ ọmọ bibi idagbasoke Ìgbómìnà, Ìgbómìnà Descendants Development Union, (IDPU), Barisita A. S Salami, to ba awọn oniroyin sọrọ ni ni nnkan bii aago meje alẹ ku iṣẹju diẹ lojo ọhun bẹrẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, bi ojo naa ṣe n rọ ni iji nla n fẹ.

Aarẹ ọhun ni iji jija lo kọkọ ṣaaju, ki ojo too bẹrẹ si i rọ. O ni gbogbo ile to wa laduugbo Ìgbómìnà, ni iji naa fẹrẹ fọwọ ba tan, to si gbe odidi ile, tabi ko ba a jẹ.

Salami, ni iji nla naa ti mu adanu nla ba ọpọ araalu to ṣoro fun wọn lati ribi sun si bayii.

O bẹ ijọba atawọn tori ṣẹgi ọla fun lati dide iranlọwọ fawọn to fara kaasa, nitori ọpọ dukia olowo iyebiye lo ṣegbe latari ojo nla to rọ lẹyin iji naa, ọpọ lo ti di alainilelori lasiko ti gbogbo nnkan di ọwọngogo yii.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hakeem Hassan Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin yii, o ni iṣẹlẹ naa ba ni lọkan jẹ pupọ, ati pe awọn to fara kaasa ti n beere fun iranlọwọ ijọba.

Leave a Reply