Ijinigbe akẹkọọ Zamfara: Awọn obi fibinu ya bo ileewe, wọn ba dukia ijọba jẹ

Faith Adebọla

Latari bawọn agbebọn ṣe ji awọn akẹkọọ-binrin to ju ọọdunrun lọ gbe nileewe ijọba Government Girls Secondary School, nipinlẹ Zamfara, awọn kan lara obi awọn awọn ọmọ naa ti lọọ ṣakọlu si ileewe ọhun, wọn si fibinu ba awọn dukia ijọba jẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, bojumọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ṣe n mọ, lẹyin tiṣẹlẹ ijinigbe naa ti waye loru, awọn obi naa sare gba ileewe ọhun lọ, ni Jangebe, nijọba ibilẹ Talata-Mafara, onikaluku fẹẹ mọ boya ọmọ wọn ko si lara awọn ti wọn ko wọgbo ọhun.

Wọn ni iyalẹnu lo jẹ fawọn obi naa nigba ti wọn ri i pe awọn ọmọ to ṣeku ko fi ju aadọta (50) pere lọ, bẹẹ wọn lawọn ọmọ to n kawe nileewe ọhun le lẹgbẹta (600). Bakan naa ni wọn ni ọkan lara awọn tiṣa ileewe naa sọ pe awọn ọmọ ti wọn ji gbe naa ju ọọdunrun lọ daadaa, o ni wọn le lẹẹdẹgbẹta (500).

Ibinu iṣẹlẹ yii, ati ijakulẹ bijọba ko ṣe pese aabo to peye fawọn ọmọ wọn ni wọn lo fa a tawọn obi naa fi bẹrẹ si i ba awọn dukia jẹ ninu ọgba ileewe naa, wọn n gbọn windo ati ilẹkun yọ, wọn si n ba awọn aga ati tabili tawọn akekọọ naa n lo jẹ.

Bẹẹ ni wọn lawọn obi tori ko ọmọ wọn yọ lọwọ ikọlu awọn ajinigbe naa n sare gan ọmọ wọn lapa, wọn mu wọn kuro nileewe ọhun, wọn si n leri pe ọmọ awọn ko kawe mọ, ijọba ti ja awọn kulẹ.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), tun royin pe niṣe ni obi kan daku lọ gbọnrangandan nigba to ri i pe ọmọ rẹ ti wa lara awọn ti wọn ha sọwọ awọn agbebọn naa.

Amọ ṣa o, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ọmọbinrin ọmọleewe ti wọn ji gbe naa ko ju okoolelọọọdunrun o din mẹta lọ (317).

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Shehu Mohammed, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lori iṣẹlẹ naa pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ igbesẹ gidi lati tete ri awọn ọmọ okoolelọọọdunrun o din mẹta naa gba wale pada.

Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, Abutu Yaro, olori ikọ Hadarin Daji tileeṣẹ ologun, Ọgagun Aminu Bande, kọmanda awọn ọmọ ogun birigeedi ki-in-ni lẹka ileeṣẹ ologun to wa ni Gusau, atawọn oṣiṣẹ ijọba tọrọ kan ti dide sọrọ yii, wọn kọkọ lọ sileewe tiṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ ni Jangebe, lati le tọpasẹ igbo ti wọn ko wọn lọ ati apa ibi ti wọn gba.

Kọmiṣanna ọlọpaa ti ba ọga agba (Principal) ileewe naa atawọn obi tinu n bi sọrọ, o si ti bomi suuru fun wọn mu, o ti fi da wọn loju pe agbarijọ awọn ẹṣọ eleto aabo, awọn ọlọpaa, awọn ṣọja atawọn fijilante ni wọn maa ṣiṣẹ ọhun lati gba awọn ọmọ naa kuro lakata awọn afurasi ọdaran to ji wọn gbe naa.”

Leave a Reply