Ijọba apapọ ṣi papakọ ofurufu mẹrinla

Oluyinka Soyemi

Ijọba apapọ ilẹ Naijiria ti fọwọ si ṣiṣi awọn papakọ ofurufu mẹrinla lẹyin awọn eto ati atunṣe to waye.

Minisita feto irinna ofurufu, Hadi Sirika, lo kede ọrọ naa lonii, ọjọ Aiku, Sannde.

Awọn papakọ naa nijọba ti pa lẹyin ti arun Korona wọ Naijiria loṣu keji, ọdun yii.

Awọn papakọ ofurufu naa ni: Murtala Muhammed Murtala Muhammed International Airport, Eko; Nnamdi Azikwe International Airport, Abuja; Malam Aminu Kano International Airport, Kano; Port Harcourt International Airport, Omaguwa; Sam Mbakwe Aiport, Owerri; Maiduguri Airport, Maiduguri.

Awọn to ku ni: Victor Attah Airport, Uyo; Kaduna Airport, Kaduna; Yola Airport, Yola; Margaret Ekpo Airport, Calabar; Sultan Abubakar Airport, Sokoto; Birnin Kebbi Airport, Kebbi; Yakubu Gowon Airport, Jos; ati Benin Airport, Benin.

Lọwọlọwọ bayii, Victor Attah Airport, tilu Uyo, nikan lo laṣẹ lati gbalejo baluu to n lọ tabi pada lati oke-okun.

Leave a Reply