Faith Adebọla
Ohun to ti lọ tun ti pada bọ, pẹlu bijọba apapọ ṣe buwọ lu ofin idasilẹ ati kikọ awọn too-geeti si awọn ọna marosẹ to jẹ tijọba apapọ kaakiri orileede yii.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni igbimọ apaṣẹ tijọba apapọ, Federal Executive Council, buwọ lu iwe ofin kikọ too-geeti lati maa gba owoobode lọwọ awọn onimọto, ati iye owoobode ti wọn yoo maa san lasiko ipade ọsọọsẹ wọn, eyi ti Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, dari nileejọba l’Abuja.
Minisita fun iṣẹ ode ati ile gbigbe nilẹ wa, Amofin Babatunde Raji Faṣọla, ṣalaye lẹyin ipade naa pe ijọba to wa lode yii ti ṣiṣẹ ribiribi lori atunṣe awọn ọna apapọ kaakiri orileede yii, wọn si ti kọ awọn ọna tuntun mi-in, eyi lo fa a tawọn fi pinnu lati da iṣeto gbigba owoobode pada, lati le maa rowo ṣatunṣe sawọn ọna naa loorekoore.
O lawọn ti fọrọ yii to awọn tọrọ eto irinna kan, awọn si ti fikun lukun pẹlu awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lẹka eto irinna, titi kan awọn ẹgbẹ ọlọkọ NURTW (National Union of Road Transport Workers) ati RTEAN (Road Transport Employees Association of Nigeria, atawọn mi-in, kawọn too gbe ofin naa kalẹ.
Bakan naa ni minisita sọ pe ijọba apapọ ti fọwọ si i kawọn ọlọkọ ayọkẹlẹ (cars) maa san igba naira (N200), awọn jiipu (SUVs) yoo maa san ọọdunrun naira (N300), bọọsi akero yoo maa san aadọjọ naira (N150), awọn bọọsi ajagbe ati awọn ọkọ akẹru yoo maa san ẹẹdẹgbẹta naira (N500).
O tun ṣalaye pe kidaa awọn ọna marosẹ tijọba apapọ ti ọkọ meji meji n rin ẹgbẹ kọọkan rẹ lawọn yoo ti maa gba owoobode, o si gbọdọ jẹ ọna ti wọn fi kọnkere pin si meji laarin.
Yatọ si fifi owo ti wọn ba pa tun awọn ọna yii ṣe, o lawọn tun ni lati da gbese owo tawọn ya lawọn banki pada ninu owo ọhun.
Amọ ṣa o, Faṣọla ni sisan owoobode ko ni i kan awọn to n gun kẹkẹ, ọkada, kẹkẹ Marwa, ọkọ awọn aṣoju ijọba okeere, tawọn ologun atawọn agbofinro tiṣẹ wọn jẹ mọ toloogun.
Bakan naa lo ni awọn maa din iye owoobode tawọn to n gbe lagbegbe too-geeti yoo maa san ku, tori bi wọn ṣe n ṣe e kari aye niyẹn.