Ṣoyẹmi Oluyinka, Ekiti
Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ekiti, Akin Ọmọle, ti sọ pe awọn ko ko ṣọja jade lati dunkooko mọ awọn ọdọ to n ṣewọde SARS, bi ko ṣe lati daabo bo wọn, ko ma baa si pe wọn n pa ẹnikẹni ninu wọn tabi ki awọn ọmọọta ma gba iwọde naa mọ wọn lọwọ debi to fi maa da wahala silẹ niluu lawọn fi ṣe bẹẹ.
O ni ko soootọ ninu iroyin ti wọn n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara pe ṣoja ti gba gbogbo Ado-Ekiti, ti wọn si n fi ibọn le aọn to ṣewọde kiri.
‘’Awọn ṣoja wa niluu lati daabo bo gbogbo araalu, to fi mọ awọn to n fẹhonu han naa, ati lati ma jẹ ki awọn tọọgi ja iwọde naa mọ wọn lọwọ ni,’’ Ọmọle lo sọ bẹẹ.
O ni bo tilẹ jẹ pe ijọba to wa nita fara mọ ẹtọ ti awọn eeyan naa ni lati fi ẹhonu han, eyi ko ni ki wọn di alaafia awọn araalu lọwọ, bẹẹ lawọn si gbọdọ pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu.