Faith Adebọla, Eko
Omije ẹkun awọn mọlẹbi Oloogbe Kudirat Adebayọ Abayọmi ti yipada dayọ pẹlu bijọba ṣe fun wọn lẹbun miliọnu mẹwaa naira (#10 million) lati fi ṣeranwọ fun wọn latari aṣita ibọn ọlọpaa to da ẹmi ẹni wọn legbodo loṣu kẹrin, ọdun 2017.
Bakan naa ni wọn tun fun Abilekọ Hannah Olugbode lowo, ẹni ọdun marundinlogoji, to jẹ pe kẹkẹ awọn arọ lo fi n rin latigba ti aṣita ibọn kan ti fọ eegun ẹsẹ osi rẹ lagbegbe Ijeṣatẹdo, nipinlẹ Eko. Miliọnu mẹwaa naira ni wọn nawọ rẹ soun naa (#10 million).
Nibi ijokoo igbimọ to n gbọ ẹjọ awọn tọlọpaa SARS fiya jẹ lọna aitọ (The Lagos State Judicial Panel of Enquiry and Restitution for Victims of Special Anti-Robbery Squad) lọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn ti da awọn mọlẹbi mejeeji lọla.
Yatọ si ti owo, ijọba tun pese ẹkọ-ọfẹ fawọn ọmọ ti awọn obinrin mejeeji ọhun bi, wọn lawọn maa ran wọn niwee de fasiti.
Igbimọ naa tun dabaa pe kijọba ba awọn ọlọpaa tọrọ aṣita ibọn naa kan ṣẹjọ, ki wọn le mọ pe iṣẹ ọlọpaa ko sọ wọn di ẹni to ti ga kọja ofin, ki eyi si le jẹ arikọgbọn fawọn agbofinro mi-in.
Bakan naa ni wọn ni kileeṣẹ ọlọpaa ko lẹta sawọn mọlẹbi mejeeji lati tọrọ aforiji fun iṣẹlẹ to sọ awọn eeyan wọn di oloogbe ati alaabọ ara lai ro ti.
Iṣẹ aṣerunloge ni wọn ni Abilekọ Hannah n ṣe, ṣugbọn latigba tiṣẹlẹ aburu naa ti ṣẹlẹ si i lo ti n nawo sori itọju ọgbẹ ti aṣita ibọn naa mu ba a, pẹlu ọpọ irora, ti nnkan ko si rọrun foun atawọn mọlẹbi rẹ.
Eyi ni igba akọkọ ti igbimọ yii yoo fawọn eeyan tọlọpaa ti tẹ ẹtọ wọn mọlẹ lẹbun owo nla bii eyi, yatọ seyii ti gomina ipinlẹ Eko fọwọ ara rẹ fawọn mọlẹbi kan ninu loṣu kejila, ọdun to kọja.