Ijọba fẹẹ lu awọn mọto ti wọn ṣẹ sofin irinna ni gbanjo l’Ekoo

Jide Alabi

Ijọba Eko ti kede pe awọn maa lu awọn mọto ti wọn mu lori ẹsun pe wọn fi lu ofin irinna ni gbanjo.

Akọwe iroyin gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akọsile, lo kede ọrọ ọhun sori ikanni abẹyẹfo ẹ, nibi to ti sọ pe gbogbo eto lo ti pari bayii lori bi ijọba ṣe fẹẹ lu awọn mọto tiye wọn  jẹ mẹrinlelogoji (44) ni gbanjo gẹgẹ bi ofin irinna Eko ti ṣe la a kalẹ.

Awọn mọto ti wọn fẹẹ ta yii lawọn to ni wọn fi rufin eto irinna l’Ekoo, bẹẹ ni ile-ẹjọ ti paṣẹ  pe ijọba Eko le gbẹsẹ le wọn.

Ni bayii, ijọba Eko ti kede pe ẹni to ba nifẹẹ lati ra awọn mọto naa le yọju, ati pe awọn to ni wọn gan-an naa lanfaani lati waa ra wọn pada lọwọ ijọba.

Ofin ti wọn ni wọn fi awọn mọto ọhun lu ni bi wọn ṣe wa wọn gba oju ọna ti ko yẹ l’Ekoo, paapaa lilo ojuna ti ki i ṣe ibi tọ yẹ ki wọn gba rara.

Ibi igbe-ọkọ-pamọ si lẹyin ile itaja Shoprite, ni Alausa, n’Ikeja, l’Ekoo, ni eto ọhun yoo ti waye, bẹrẹ  ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii.

Ohun ti ijọba Eko tẹnumọ ni pe oun ko ni i gba ẹnikẹni laaye lati ba ilu Eko jẹ, paapaa nipa riru ofin irinna.

 

Leave a Reply