Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti ni ko si awijare tabi awawi kan latọdọ awọn onimọto to ba lufin irinna nipinlẹ naa, onimọto maa dele-ẹjọ, mọto ọhun si maa ha sakolo ijọba ni, eyi lohun to ṣẹlẹ sawọn ọkọ mọkandinlaaadọta tọwọ awọn agbofinro tẹ, titi kan ambulansi agbokuu-gbalaaye kan.
Alaga ikọ amuṣẹṣe (Taskforce) lori ọrọ ayika ati lilọ bibọ ọkọ, Ọgbẹni Shola Jẹjẹloye, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Aiku, Sannde yii, o ni eyi to pọ ju lara awọn mọto ti wọn faṣẹ ọba gba ọhun jẹ nitori wọn n gba ọna ọlọna tabi ki wọn gba ọna akanṣe to wa fun ọkọ BRT nikan.
O ni ambulansi tawọn mu naa gba ọna BRT ni, awọn si ṣakiyesi pe ko si iṣẹlẹ pajawiri kan to le mu ko gba ọna ọlọna bẹẹ, wọn ni dẹrẹba ọkọ naa jẹwọ pe oun fẹẹ lọọ ra nnkan kan fun ara oun ni.
Shọla ṣalaye pe o fẹrẹ jẹ gbogbo awọn awakọ tawọn mu nibi ti wọn ti n rufin irinna naa lo jẹwọ pe loootọ lawọn mọ nipa ofin irinna tijọba Eko ṣe lọdun 2018, ṣugbọn nitori oju to n kan awọn lawọn fi gba ọna ọlọna, awọn fẹẹ tete debi tawọn n lọ ni.
Alaga naa ni awọn maa wọ awọn onimọto yii ati ọkọ wọn dele-ẹjọ, o si ṣee ṣe ki wọn padanu awọn ọkọ naa sọwọ ijọba, tile-ẹjọ ba paṣẹ bẹẹ.
O nijọba ko ni i gba gbẹrẹ pẹlu onimọto to ba tapa sofin irinna tabi to n gba ọna ọlọna lasiko yii, ko si saaye fun ẹbẹ tabi owo abẹtẹlẹ, ẹnikẹni to ba ṣẹ sofin yoo kawọ pọnyin rojọ ni.