Ijọba ipinlẹ Ọṣun fagi le Yidi Iasiko Ileya lati dena itankalẹ arun Korona

Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, ti kede pe ko ni i si anfaani fun awọn Musulumi lati kora jọ ni Yidi fun adura ọdun Ileya lọdun yii.

Ṣugbọn anfaani wa fun wọn lati lọ si adura Juma’at, niwọn igba to jẹ pe ọjọ Jimọh naa ni ọdun Ileya ọhun bọ si.

Eleyii ko ṣẹyin imọran ti awọn oṣiṣẹ eto-aabo fun ijọba latari bi awọn kan ṣe kọ etiikun si gbogbo ikilọ rẹ lori ọrọ arun Korona.
Oyebamiji ṣalaye pe ibẹsilẹ arun naa yoo lagbara si i tijọba ba le faaye gba ọpọ eeyan lati tun pe jọ soju kan fun adura nitori aimọye awọn ọlọdun ni wọn ti wọle lati oriṣiiriṣii ilu.

O waa ran wọn leti pe gbogbo ilana to jẹ mọ lilo ibomu ati iboju, jijina sira ẹni, fifọ ọwọ pẹlu ọṣẹ ati omi, pẹlu lilo sanitaisa ni wọn gbọdọ tẹle nibi adura Juma’at ti wọn ba n ṣe.

Leave a Reply