Minisita fun eto iroyin nilẹ wa, Alaaji Lai Muhammed, ti sọ pe ijọba ko ni i faaye gba iwọde ti awọn ọdọ kan n sọ pe awọn yoo kora awọn jọ lati ṣe ni Too-Geet Lẹkki, nipinlẹ Eko, gẹgẹ bo ṣe waye lọjọsi.
LaI Muhammed ni yatọ si pe Lẹkki yii ki i ṣe ibi ti awọn eeyan le maa pejọ si lati ṣe iwọde nitori pe ki i ṣe ohun to wa fun niyẹn, ijọba ko tun ni i laju rẹ siẹ ki awọn kan tun maa da ilu ru.
O sọrọ naa niluu Abuja, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa iwọde ti awọn ọdọ kan tun n sọ pe awọn fẹẹ gun le ni ọjọ Abamẹta,Satide, opin ọsẹ yii.
Ọkunrin naa ni bo tilẹ jẹ pe o wa ninu ofin ilẹ wa pe awọn eeyan le fi ẹhonu wọn han, sibẹ, wọn gbọdọ ṣe e nibi ti ijọba fọwọ si fun wọn lati ṣe e, nitori Lẹkki ki i ṣe ile ifẹhonu han.
Bẹẹ lo ni awọn agbofinro yoo wa larọọwọto lati ri i pe ko si ifẹhonu han to tun le fa wahala tabi ijamba ati ifi dukia ṣofo to waye lọjọsi.
Ṣugbọn pẹlu ikilọ yii, awọn ẹgbẹ ti wọn fẹẹ ṣewọde Lẹkki yii ni ko si iru idunkooko tabi ihalẹ ijọba to le mu ki awọn ma ṣe iwọde ni Satide yii.
Bakan naa ni Gomina Babajide Sanwo-Olu kilọ pe ko gbọdọ si iwọde kankan, bẹẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ gun le ohun ti yoo da alaafia ipinlẹ Eko ru tabi ti yoo tun mu wọn ni iru iriri ti wọn ni ninu oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, nibi ti ọpọ ile, dukia ati ẹmi ti ṣofo lori ifẹhonu han ta ko SARS.
Ọjọ Abamẹta yii ni awọn eeyan n duro de lati mọ boya ọrọ Lai Muhammed ni yoo ṣẹ ni abi ti awọn ọdọ to fẹẹ ṣewọde.