Gomina ipinlẹ Eko tele, Lateef Jakande, ti ku o

Alhaji Lateef Jakande, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, ti jade laye lẹni ọdún mọkanlelaaadọrun-ùn.
Owurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn sọ pe baba naa jade laye.
Akọroyin ni gomina Eko yii tẹlẹ, bẹẹ lo ṣejọba Eko laarin ọdún 1979 sí ọdún 1983.
Bakan naa ni wọn tún fún ùn nipo
mínísítà ọrọ iṣẹ ninu ijọba Sanni Abacha.


Titi di asiko yii ni awọn eeyan gbagbọ pe ijọba ẹ ṣiṣẹ takuntakun paapaaa lori ipese ohun amayederun bíi ileegbe, ileewe atawọn ọsibítù kaakiri ipinlẹ Eko.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun to ṣokunfa iku baba yii la o máa mú wa laipẹ.

Leave a Reply