Ijọba Kwara fẹẹ sọ ibudo imọkoko Dada di tigbalode -Oyin-Zubair

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ni idaahun si ẹbẹ awọn to n ṣe ikoko ibilẹ nibudo to gbajumọ daadaa lagbegbe Dada, niluu Ilọrin, ijọba ipinlẹ Kwara ti ni eto ti n lọ lọwọ lati sọ ibudo naa di ti igbalode nipa ipese awọn ohun eelo ti yoo mu iṣẹ rọrun fawọn amọkoko naa.

Oluranlọwọ pataki fun Gomina Abdulrahman Abdulrazaq nipa ọrọ ilu, SSA Community Intervention, Ọgbẹni Kayọde Oyin-Zubair, lo sọrọ ọhun nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn obinrin to n mọ ikoko ni Dada, niluu Ilọrin.

Oyin-Zubair ni, ṣiṣe igbelarugẹ awọn okoowo keekeeke to tun jẹ tibilẹ bii ti ikoko mimọ yii jẹ ijọba Kwara logun gidi. Idi niyi tijọba fi ri i pe pupọ lara awọn obinrin to n ṣe iṣẹ naa janfaani owo iranwọ fawọn oniṣowo kekeeke eyi to waye laipẹ yii.

O tẹsiwaju pe pataki ohun to gbe ijọba wa sibudo naa ni lati tun fi da awọn obinrin naa loju pe ijọba fẹẹ mu aye dẹrun fun okoowo wọn lati sọ ọ di igbalode ati ape-waa-wo fun agbaye.

Awọn obinrin naa fi idunnu wọn han si bi aṣoju gomina ṣe waa bẹ wọn wo. Wọn lo anfaani naa lati dupẹ lọwọ ijọba fun owo iranwọ ti ọpọlọpọ wọn janfaani.

Ṣaaju ni Alhaja Raliat Saka to jẹ adari awọn obinrin to n mọ ikoko nibudo Dada ti beere fun awọn ẹrọ igbalode lati mu ki iṣẹ wọn rọrun ati ko si tun joju ju bo ṣe wa lọ.

 

Leave a Reply