Ijọba Kwara san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira owo-osu oṣiṣẹ to kere ju lọ

Ibrahim Alagunmu,  Ilọrin

Wọn ni inu didun ni i fa ijo ajorin lọna oko, ijọba Kwara labẹ iṣejọba Gomina Abdulrazak, bẹrẹ sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira owo-osu oṣiṣẹ to kere ju lọ, lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni awọn oṣiṣẹ ba n jo jagini yodo, ti wọn n fo fayọ.

Lọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba jake-jado ipinlẹ Kwara, bẹrẹ si i jo, ti wọn si n yọ, bẹẹ ni wọn n dupẹ lọwọ GominaAbdurahman Abdulrazaq, fun bo ṣe gbe igbeṣẹ akin, to bẹrẹ si i san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira owo-osu to kere ju lọ, to si tun san owo igbega lẹnu iṣẹ lẹsẹkẹsẹ fawọn oṣiṣẹ ọhun.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Kwara, labẹ  TUC, NLC ati JNC, dupẹ lọwọ gomina fun bo ṣe mu adehun rẹ ṣẹ pẹlu bii nnkan ṣe le koko bii oju ẹja.

Wọn tun gbadura pe gbogbo ohunkohun ti gomina ba nawọ si, ọwọ rẹ yoo maa to o.

 

Leave a Reply