Ijọba Naijiria n binu si ileeṣẹ iroyin CNN, wọn ni ayederu iroyin lo gbe lori ọrọ Lẹkki

Dada Ajikanje

Ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti bu ẹnu atẹ lu bi ileeṣẹ iroyin CNN ṣe gbe iroyin pe ọpọlọpọ eeyan lawọn ẹṣọ agbofinro pa nipakupa lasiko tawọn ṣọja kọ lu awọn ọdọ to n ṣewọde ni Lẹkki, l’Ekoo.

Wọn ni irufẹ iroyin bẹẹ, bii ẹni ṣiṣẹ ẹ lọna ti ko bojumu to ni, nitori awọn nnkan ti ko ṣẹlẹ tawọn eeyan kan n pin kiri ori ẹrọ ayelujara ni ileeṣẹ tẹlifiṣan ọhun tẹle, to fi kede ẹ fun gbogbo aye pe oku rẹpẹtẹ lo sun ni Lẹkki.

Ṣiwaju si i, ijọba Naijiria ti sọ pe pupọ ninu ohun ti CNN gbe jade nipa wahala to ṣẹlẹ ni Lẹkki ni awọn iroyin ti ki i ṣe ootọ tawọn eeyan kan n gbe sori ikanni ayelujara wọn, eyi ti wọn fẹẹ fi sọ ileeṣẹ oloogun Naijiria lẹnu gẹgẹ bo ṣẹlẹ lagbegbe Lẹkki, l’Ekoo, logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii

Leave a Reply