Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki awọn araalu yọ gbogbo awọn geeti ti wọn ṣe si ibẹrẹ ati ipari awọn opopona wọn lai gba iwe aṣẹ ijọba kuro laarin ọjọ meje pere.
Kọmiṣanna eto irinna, Dokita Frederic Ọladẹinde, lo sọ bẹẹ lorukọ Gomina Babajide Sanwo-Olu, ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ọladẹinde sọ pe ko bofin mu rara, o si ya ijọba ipinlẹ Eko lẹnu lati ri i pe ọpọlọpọ opopona lawọn eeyan ri geeti gagara mọ bo ṣe wu wọn, ti wọn tun ṣofin asiko ti wọn aa maa ṣi geeti naa tabi ti wọn aa maa ti i, bẹẹ wọn ko gba aṣẹ lati ṣe iru nnkan bẹẹ latọdọ ijọba. O ni ẹka eto irinna (ministry of transport) leeyan ti le gba iru aṣẹ bẹẹ.
Kọmiṣanna ni awọn geeti ti wọn ṣe naa n ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ, o mu ko ṣoro fawọn ọnimọto lati gba awọn ọna abuja ati horo to le din iṣoro sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ lawọn ọna nla ku. Yatọ si eyi, o lawọn geeti naa tun ta ko ẹtọ ati ominira tawọn araalu ni lati rin falala nigbakigba, ati nibikibi to ba wu wọn.
Pẹlu atẹjade yii, o ni kawọn to ba ni irufẹ geeti tijọba ko fontẹ lu bẹẹ tete hu u kuro laarin ọjọ meje, tabi ki wọn ṣi i silẹ gbayawu laarin aago marun-un owurọ titi di aago mejila oru lojoojumọ, aijẹ bẹẹ, awọn ikọ amuṣẹya kan tijọba ti gbe kalẹ yoo maa lọ kaakiri, wọn yoo si hu awọn geeti ti ko bofin mu naa danu.
Fun awọn to ba niwee aṣẹ paapaa, Frederic ni ofin ni pe ki wọn ṣeto ẹni kan bii getimaanu ti yoo maa wa nidii geeti naa nigba gbogbo.
Kọmiṣanna naa rọ awọn araalu to ba niwee aṣẹ geeti wọn lọwọ pe ki wọn yọju si ẹka irinna ọkọ tipinlẹ Eko pẹlu iwe aṣẹ tijọba fun wọn lati mu iwe naa ba igba mu, kawọn ti ko ba si niwee ṣe ohun to yẹ gẹgẹ bii alaye toun ṣe soke yii.