Stephen Ajagbe, Ilorin
Ni ibamu pẹlu aṣẹ ajọ n to n gbogun ti arun, lorilẹ-ede Naijiria, NCDC, ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ilera kaakiri awọn ọsibitu ijọba lati maa kọkọ ṣe ayẹwo fun alaisan to ba tọ wọn wa lati mọ boya onitọhun ni awọn apẹrẹ arun Covid-19 lara, ko too di pe wọn ṣe itọju rẹ.
Bakan naa ẹwẹ, wọn ni ko si ilewosan aladaani kankan tajọ NCDC fontẹ lu lati tọju arun Korona ni Kwara o, fun idi eyi, kawọn araalu ṣọra gidi, bẹẹ si ni kawọn ilewosan bẹẹ maa juwe ọna ibudo itọju Covid-19 to wa ni Sobi, Alagbado fawọn alaisan ti wọn ba ri i pe wọn ni apẹẹrẹ rẹ lara.
Alaga igbimọ to n mojuto Covid-19 nipinlẹ Kwara, to tun jẹ Igbakeji gomina, Kayọde Alabi, lo ṣe ikede naa ninu atẹjade kan l’Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii.
O ni awọn to ba fẹẹ ṣe ayẹwo le lọ sawọn ibudo tijọba ti gbe kalẹ kaakiri olu ijọba ibilẹ kọọkan, laarin aago mẹsan-an aarọ si marun-un irọlẹ ojoojumọ laarin ọsẹ nikan.
Alabi ni esi ayẹwo teeyan ba ṣe maa bẹrẹ si i jade laarin wakati mẹrinlelogun.
O ke si awọn oṣiṣẹ ilera lati maa tete tọka ibudo itọju arun, Covid-19/Infectious Disease Centre Sobi (Alagbado) sawọn to ba ni apẹẹrẹ rẹ ki wọn le gba wọn nimọran nipa ọna ti wọn fi le yẹ ara wọn sọtọ ninu ile wọn, ki wọn si takete sawọn ara ile mi-in ti ko ni i lara.
O ni to ba ni ohunkohun tawọn araalu ba fẹẹ beere tabi fi to ijọba leti, wọn le pe sori awọn nọmba wọnyi; 09062010001, 09062010002, 09010999937, 09010999938.