Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ni imurasilẹ fun idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede ọjọ Ẹti, Furaidee, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ araalu, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita ṣalaye pe eredi isinmi naa ni lati fun awọn araalu lanfaani lati lọ sijọba ibilẹ ti wọn ba ti fẹẹ dibo.
Ẹgbẹmọde sọ siwaju pe ko ni i si aaye fun irinkerindo ọkọ lati aago meje aarọ ọjọ Abamẹta ti idibo yoo waye titi di aago mẹta ọsan.
Ijọba rọ awọn araalu lati tu yaaya jade lati dibo yan awọn aṣoju wọn kaakiri ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ọṣun.
Bakan naa ni wọn rọ awọn obi ati alagbatọ lati ba awọn ọmọ wọn sọrọ nibi ti wọn ti maa n gbọrọ pe ki wọn ma ṣe faaye gba ẹnikẹni lati lo wọn fun idarudapọ tabi jagidijagan lasiko idibo naa.