Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latari ikọlu oriṣiiriṣii to n waye lẹnu ọjọ mẹta yii nilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun, laarin awọn Fulani atawọn Yoruba, ijọba ipinlẹ yii ti ni kawọn to ba nifẹẹ lati darapọ mọ ikọ naa waa gba fọọmu.
Ẹ oo ranti pe ninu oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ni wọn ti kọkọ kede pe ikọ Amọtẹkun yoo bẹrẹ iṣẹ nipinlẹ yii, ijọba si ti bẹrẹ igbesẹ naa bayii pẹlu fọọmu ti wọn ni kawọn eeyan maa waa gba.
Agbẹnusọ Gomina Dapọ Abiọdun lori eto iroyin asiko yii, Emmanuel Ojo, lo fi atẹjade to n kede iforukọsilẹ naa sita l’Ọjọbọ, ọjọ kọkanla, oṣu keji yii.
Lati gba fọọmu naa, ẹka igbanisiṣẹ nipinlẹ Ogun ni eeyan yoo lọ, eyi ti i ṣe oju opo http://jobs.ogunstate.gov.ng/job/ogun-state-security-network-agency-amotekun-corps-878. Beeyan ko ba ba si fẹẹ ṣe eyi, o le lọọ gba fọọmu naa ni ọfiisi awọn So-Safe ipinlẹ Ogun, eyi to wa ni Oke-Ilewo, l’Abẹokuta.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji yii, ni gbigba fọọmu yoo kasẹ nilẹ gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ.
Ko saaye a n gba fọọmu lẹẹmeji bi wọn ṣe wi, wọn ni bi orukọ ẹni kan ba yọ lẹẹmeji, wọn yoo yọ iru fọọmu bẹẹ danu ni.