Florence Babaṣọla
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi, ti sọ pe aisi itọju to peye ati amojuto lo fa a ti awọn Fulani darandaran lorileede Naijiria fi n huwa janduku, ti wọn si sọ ijinigbe di iṣẹ.
Lasiko ti Oluwoo lọ sigberiko ti awọn Fulani naa tẹdo si, nibi ti wọn n pe ni Gaa-Fulani to wa ni Odo-Ọba, niluu Iwo, lo ti rọ gbogbo awọn Fulani ti wọn n gbe nigberiko yika ilu Iwo lati ko wa sinu ilu, ki wọn si ni ibaṣepọ pẹlu awọn araalu.
O ṣalaye fun wọn pe iwa atijọ ni dida maaluu jẹ kaakiri, asiko si ti to fun awọn eeyan naa lati maa lo ọna igbalode fun bibọ awọn nnkan ọsin wọn.
Ọba Akanbi ṣalaye pe oun ti ba Aarẹ Buhari atawọn adari kọọkan lorileede sọrọ pe ki wọn ran awọn Fulani darandaran diẹ lọ si oke-okun lati lọọ kọ bi wọn yoo ṣe maa bọ awọn ẹran wọn lọna igbalode.
O ni “Ko si bi a ṣe le pa awọn kan ti sinu igbo, ka si maa reti iwa gidi latọdọ wọn. A fẹ ki ẹ maa bọ wa saarin ilu, ẹ maa gbe laarin awọn eeyan.
‘Mo lọ si Aso Rock, mo si ba Aarẹ sọrọ nipa yin, mo sọ fun Aarẹ pe ki wọn ran diẹ lara yin lọ soke-okun lati lọọ kọ bi wọn ṣe n sin nnkan ọsin lọna igbalode. Bawo ni maaluu ti ẹ mu lọọ jẹ bii ogun maili yoo ṣe sanra? Oju kan naa lo yẹ ki awọn maaluu yin wa, ki wọn si maa jẹun nibẹ”
Oluwoo tun rọ awọn Fulani naa lati gba awọn ọmọ wọn laaye lati kawe, o ni o ṣee ṣe ki eyi to ba kawe ninu wọn pa iṣẹ darandaran ti awọn obi wọn n ṣe ti.
Bakan naa lo rọ awọn ori-ade kaakiri orileede yii lati ko awọn Fulani ti wọn ti pẹ lọdọ wọn mọra, ki wọn si mu wọn bii ọmọ ilu wọn.
O waa ke si awọn Fulani ọhun lati fọwọsowọpọ fopin si wahala to n ṣelẹ kaakiri. O si gbadura pe ki Ọlọrun fọwọ tọ gbogbo awọn ti wọn n huwa janduku laaarin wọn.