Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọrọ mi-in tun bẹ sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lori bi ijọba Bukọla Saraki ati Abdulfatah Ahmed ṣe ta ọpọlọpọ ilẹ tawọn to ṣejọba lọdun 1980 ti ya sọtọ fun kikọ kootu.
Ọga agba ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ilẹ nipinlẹ Kwara, Bọlaji Ẹdun, lo sọ bayii fun igbimọ to n ṣewadii bawọn to ṣejọba lọ ṣe ta dukia ijọba lai tẹle ofin.
Ẹdun ṣalaye pe ijọba ti ya awọn ilẹ kan to wa lagbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, fun ẹka eto idajọ lati kọ awọn ile-ẹjọ si, ṣugbọn diẹdiẹ lawọn to ṣejọba bẹrẹ si i ta a lati ọdun 2009.
Ẹka eto idajọ lo kọ iwe sọwọ si igbimọ naa lori bi ko ṣe si awọn yara idajọ to too lo nipinlẹ Kwara, ti wọn si rọ igbimọ ọhun lati gba gbogbo ilẹ to yẹ ki wọn kọ ile-ẹjọ si tawọn eeyan naa ti ta pada.
Candidate Hotel ati ẹgbẹ awọn onimọ-ẹrọ, Nigeria Society of Engineering, ti gba lara ilẹ ọhun, ti wọn kọ otẹẹli ati ile ẹgbẹ wọn si.
O tẹsiwaju pe lati ileejọsin Rhema Chapel, to wa ni Tankẹ, Tipper Garage, titi de ile Ọmọọba Gambari to wa ni Tankẹ Ilẹdu, lawọn to ṣejọba ṣaaju ya sọtọ fun ẹka eto idajọ lọdun 1980.
Bakan naa, Wọnlẹ-wọnlẹ agba nipinlẹ Kwara ( Surveyor-General), Ibrahim Muhammad, jẹrii si ohun ti Ẹdun sọ, o ni gbogbo ilẹ naa jẹ ti ẹka eto idajọ, oun ko si ri akọsilẹ kankan to fi han pe ijọba gba a pada lọwọ ẹka yii ko too ta a fawọn eeyan.