Adewale Adeoye
Ni bayii, ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ tita epo bẹntiroolu nilẹ wa, ‘Nigeria Midstream And Downstream Petroluem Regulatory Authority’ (NMDPRA), ti sọ ọ di mimọ pe marundinlọgọrin (75 Filling Stations), lara awọn ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu nipinlẹ Ọṣun lawọn ti ti pa patapata nitori pe wọn ko tẹle aṣẹ ati ilana tawọn alaṣe ijọba ilẹ yii gbe kalẹ lori tita epo bẹntiroolu ọhun.
Ọga agba ajọ naa, ẹka ti ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Kunle Adeyemọ to sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Weside, ọjọ kẹwaa, osu Karun-un, ọdun 2023 yii, o ni idi pataki tawọn ṣe ti awọn ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu kọọkan pa nipinlẹ naa ni pe wọn ko tẹle awọn ilana to rọ mọ tita epo naa rara.
Lara awọn ẹṣẹ tawọn ileeṣẹ elepo ọhun ṣẹ ni pe ọpọ lara wọn ni wọn ko ni awọn ojulowo iwe aṣẹ lati maa ta epo bẹntiroolu ọhun rara, ṣugbọn ti wọn n ta a, eyi to lodi sofin ilẹ yii patapata.
O ni, ‘Ṣe la lọ kaakiri aarin ilu nipinlẹ Ọṣun, ko si igberiko kan ta a ko de tan, ileeṣẹ ti wọn ti n ta epo bẹntiroolu mọkanlelọọọdunrun (301) ni wọn wa nipinlẹ Ọṣun bayii, lẹyin ta a yẹ awọn iwe aṣẹ gbogbo ti wọn ni lọwọ wo, a ri i pe awọn bii marundinlọgọrin ni wọn ko niwee to jẹ ojulowo lọwọ rara, ta a si ti gbogbo wọn pa loju-ẹsẹ.
‘Eyi ṣe pataki pupọ nitori pe a ko fẹ awọn awuruju ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu rara nipinlẹ Ọṣun yii.
Igbesẹ ta a gbe yii waye ninu oṣu Kẹrin lọdun yii, ta a si tun maa tẹsiwaju si i. A n fi akoko yii rọ gbogbo awọn oniṣowo ọja epo bẹntiroolu gbogbo ti wọn wa ninu ilu pe ki wọn lọọ gba awọn ojulowo iwe-ẹri wọn lọdọ ijọba ko too di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii, bi bẹẹ kọ, a maa ti gbogbo awọn ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu tọwo ba tẹ pe wọn n taja naa lai jẹ pe wọn niwee ẹri gidi lọwọ ni’.