Olori ẹgbẹ awọn ọmọ Biafra ni gbogbo ilẹ Ibo ati kaakiri agbaye, Nnamdi Kanu, ti ko si akolo awọn agbofinro ni Naijria. Minisita fun eto idajọ ilẹ wa, Abubakar Malami lo kede bẹẹ laarin awọn oniroyin, nibi ti oun atawọn ọga amunifọba (SSS) ti n ba wọn sọrọ. Malami ni pẹlu aapọn ati ifọwọsowọpọ awọn agbofinro agbaye lawọn fi ri Kanu mu, nitori ẹ lawọn si ṣe n gbe e lọ sile-ẹjọ lẹsẹkẹsẹ.
Alaye bi wọn ti mu Kanu, ati ibi ti wọn ti mu un gan-an, ko ti i jade sita, ṣugbọn lati inu oṣu kẹṣan-an ọdun 2017 ni wọn ti n wa a. Ni ọdun 2017 yii, Kanu ja beeli ti ile-ẹjọ giga Abuja kan fun un ni, nibi ti wọn ti fẹsun kan an pe o da ẹgbẹ ti ko bofin mu silẹ, o n huwa afẹmiṣofo, o n ko awọn ohun ija ogun wọlu, bẹẹ lo mura lati doju ijọba Naijiria bolẹ.
Pẹlu iru awọn ẹsun bayii, o ṣoro ki ile-ẹjọ too le fun un ni beeli lọdun naa lọhun-un, ṣugbọn awọn eeyan rin si i, wọn si gba beeli rẹ. Bi wọn ti gba beeli Kanu loun fẹsẹ fẹ ẹ, ni awọn nnkan mi-in ba bẹrẹ si ṣẹlẹ. Ẹgbẹ awọn ọmọ Biafra ti wọn n pe ni IPOB yii tubọ gboro si i, wọn ko awọn ọmọ-ogun tiwọn dide, wọn pe wọn ni ọmọ-ogun Biafra, bẹẹ ni Kanu si n pariwo kiri gbogbo aye pe Biafra, iyẹn ilẹ Ibo, ko si labẹ Naijiria mọ, orilẹ-ede to da wa ni.
Lati igba naa ni ijọba ti n wa a, ti oun naa si n sa fun wọn. Ohun to jẹ ki wiwa rẹ tubọ le si i ni nigba ti awọn ọmọ ogun Biafra yii bẹrẹ si i koju awọn agbofinro ijọba, ti awọn ati ọlọpaa pẹlu awọn ṣọja si jọ n fija pẹẹta. Ọpọ ọlọpaa ati awọn ṣọja ni wọn ti ku nilẹ Ibo yii, ti awọn ọmọ ogun Biafra ti wọn ba kinni naa lọ ki i si i ṣe kekere. Bẹẹ ni ija naa ṣi n lọ lọwọ pẹlu, nibi ti ọpọ nnkan ijọba ipinlẹ wọn ti n bajẹ. Idi niyi ti awọn agbofinro fi waa n wa Kanu, nitori wọn nigbagbọ pe ti awọn ba ti mu un, ohun gbogbo yoo rọlẹ nilẹ Ibo.
Malami ni ọjọ Aiku, Sannde, yii lawọn mu un, ṣugbọn wọn ko ti i ṣalaye ibi ti wọn ti mu un.