Ijọba Tinubu yoo bẹrẹ si i gba owo-ori lọwọ awọn ọlọja keekeeke

Jamiu Abayomi

Ijọba Aare Bọla Ahmed Tinubu ti tun ṣe ofin kan bayii, ninu eyi ti awọn ọlọja keekeeke, awọn oni worobo yoo bẹrẹ si i san owo owo ori lori ọja wọn, eyi ti oloyinbo n pe ni “Value added Tax (VAT)”.

Ikede yii waye lọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lati ẹnu ajọ to n ri si ọrọ owo-ori (Federal Inland Revenue  Service) (FIRS). Ajọ naa sọ pe awọn ti ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ ontaja Market Traders Association of Nigeria (MATAN), lori igbesẹ tuntun tawon fẹe gbe yii lati maa gba owo ọhun lọna irọrun lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.

Wọn ni ajọṣepọ laarin FIRS ati MATAN yoo mu ilọsiwaju ba gbigba owo-ori lori ọja, (VAT) pẹlu ẹrọ igbalode, ti wọn yoo si maa da owo yii si apo ijọba.

Wọn tun sọ siwaju pe, MATAN yoo ni oju opo ayelujara ti yoo maa da awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lẹkọọ, ti wọn yoo si fun wọn ni kaadi idanimọ, eyi ti yoo jẹ ko rọrun lati gba owo-ori yii, ki wọn si tun da a pada fun FIRS.

Akọsilẹ ọhun ni, “Ero yii yoo jẹ akọkọ iru ẹ ti yoo maa lọ ilana ayelujara ati nini ibaṣepọ laarin FIRS atawọn ọlọja lati maa gba owo-ori lori ọja”.

FIRS ni ilana ati agbekalẹ yii yoo jẹ ki gbigba owo-ori lọna ilọpo dinku, wọn yoo si tun ni ibasepo pẹlu awọn agbofinro lati maa ba wọn da awọn ọmọ ita ati awọn afipa gbowo lọwọ awọn ontaja lọwọ kọ ninu ọja.

Wọn ni, “Ilana tuntun lati maa gba owo-ori ọja yii yoo jẹ ki gbogbo awọn igun ijọba mẹtẹẹta ri owo lo lati ṣe ohun meremere siluu, ti idagbasoke yoo si wa ni orile-ede Naijiria.

O tun ni awọn ọmọ ẹgbẹ MATAN yoo ni kaadi idanimọ, nọmba owo-ori ati ohun to yẹ lati mọ nipa wọn.

Leave a Reply