Faith Adebọla, Eko
Iroyin ayọ lo jẹ nigba ti Minisita fun iṣẹ ode nilẹ wa, Amofin agba Babajide Faṣọla, sọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje yii, pe gbogbo eto ti wa ni ṣẹpẹ lati pari iṣẹ atunṣe to n lọ lọwọ lori titi marosẹ Eko si Ibadan, ati pe iṣẹ naa yoo pari, ijọba yoo si ṣi ọna naa ki ọdun Keresimesi to n bọ ni Disẹmba too de. Ṣugbọn o fi kun un pe wiwakọ lori titi naa ko ba ọfẹ de o, tori ijọba maa da gbigba owo too-geeti ti wọn ti wọgi le nigba kan pada si ọna naa.
Faṣọla, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, sọ pe tori kijọba le kaju adapada gbese ti wọn ti jẹ ati owo rọgun-rọgun ti wọn na latigba ti iṣẹ atunṣe naa ti bẹrẹ lo fa a ti eto sisan too-geeti yii fi ni lati bẹrẹ pada.
Lasiko to n sọrọ lori eto tẹlifiṣan Channels kan lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje yii, Faṣọla ni ijọba Muhammadu Buhari mọ inira tawọn eeyan n koju lọna marosẹ naa latigba ti atunṣe ti bẹrẹ, awọn ko si fẹ ki idiwọ kankan tun wa fun lilọ bibọ ọkọ lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresi ati ọdun tuntun, idi niyi tawọn fi fẹẹ pari ọna naa ṣaaju asiko yii.
“Irin-ajo lati Eko si Ibadan ko gba to wakati meji mọ bayii, o ti ṣee ṣe lati paara Ibadan si Eko lẹẹmeji loojọ, a o si ti i pari iṣẹ, tori ta a ba pari ẹ, o maa tubọ rọrun ju bẹẹ lọ, amọ a o fẹẹ ṣi ọna naa ka tun ti i mọ.
“Tẹ ẹ ba ṣakiyesi, a ti n fi ami si awọn ibi to yẹ, a si ti n ṣe awọn iṣẹ pẹẹpẹẹpẹẹ gbogbo. Ijọba ipinlẹ Ọyọ la n duro de, emi ati Gomina Ṣeyi Makinde maa fẹnu ọrọ jona laipẹ.”
Bakan naa lo ni ijọba maa pari iṣẹ afara odo Niger keji, lapa Guusu/Ila-Oorun ilẹ wa, ki ọdun 2022 yii too tẹnu bepo.