Oludari ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ ode nipinlẹ Eko, Olukayọde Popoọla, ti kede pe odidi wakati mejilelaaadọrin (72hrs), ni wọn yoo fi ti oju ọna afara ẹlẹẹkẹta to wa niluu Eko (Third Mainland Bridge). Eyi ko sẹyin kankere biriiji naa ati awọn iṣẹ mi-in ti wọn fẹẹ ṣe nibẹ lati le mu ki afara naa duro daadaa.
Lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo sọrọ naa gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN), ṣe fi lede. Oru Satide titi di oru ọjọ Iṣẹgun ni wọn yoo fi ti afara yii pa.
Popoọla ni awọn ti ba iṣẹ oju ọna naa debi ti awọn yoo ti ṣe kankere awọn oju mẹta ti awọn fẹ̀ si i nibi ọna ọhun. O ni ọna naa yoo wa ni titi patapata ni lati le ṣe kankere oju mẹta ti awọn fẹ̀ si i yii.
O fi kun un pe lati aago mejila oru ọjọ ọdun Keresi, iyẹn ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, lawọn yoo fi ti ọna yii, eyi ti yoo fun awọn araalu lanfaani lati lo o lọjọ ọdun. O ni nigba ti yoo ba fi di aago mejila oru yii, pọpọṣinṣin ọdu Keresi yoo ti kuro nilẹ, eyi yoo si fun awọn ni anfaani lati ṣe ohun ti awọn fẹẹ ṣe.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn lo ni awọn yoo po kankere naa, awọn yoo si tun ṣe omi-in ni ọjọ kẹtadinlọgbọn.
Popoọlá ni tawọn ba ṣe eleyii, awọn nilo wakati mejilelaaadọrin ki kankere naa le to daadaa, ko si bọ si oju ibi to yẹ ko wa ko ma baa di pe afara naa n gbọn.
Ọkunrin yii ṣalaye pe ti awọn ba fi le ṣi ẹgbẹ kan afara naa silẹ fawọn ọkọ lati maa rin, o ṣee ṣe ko ṣakoba fun eyi ti awọn ṣẹṣẹ ṣe yii, ti yoo si maa gbọn ti awọn ọkọ ba ti n kọja lori rẹ. Idi niyi to fi ni oru ọjọ kejidinlọgbọn lawọn maa too ṣi afara naa pada.
Olukayọde ni gbogbo awọn ọna mi-in ti awọn eeyan le maa gba lo wa ni ipo to dara, bẹẹ ni awọn ti yoo maa mojuto lilọ bibọ ọkọ ti wa nikalẹ lati ri pe ko si sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ loju popo. O waa rọ awọn awakọ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn to n dari oju ọna naa.
Siwaju si, Popoọla ni awọn yoo tun ti apa kan oju ọna marosẹ Eko s’Ibadan naa lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila yii, si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu naa. Igbesẹ yii yoo waye lati pari iṣẹ lori awọn biriiji to wa lawọn ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ọhun lagbegbe Mountain of Fire.
Wakati mejidinlaaadọta (48hrs) lo ni apa kan ọna naa yoo fi wa ni titi.
O fi kun un pe ileeṣẹ Julis Berger to n ṣe ọna naa ti gbe awọn opo afara yii duro, ki wọn kan tẹ awọn nnkan sori rẹ ni.
Oru ọjọ kejidinlọgbọn lo ni awọn yoo ti apa kan oju ọna yii to jade lati Eko, ti awọn yoo si ṣi i pada ni aarọ kutu ọjọ keji, ni bii aago marun-un idaji.
Ọjọ kọkandinlọgbọn lo ni awọn yoo ṣe apa keji ọna naa, eyi to wọ Eko. Aago mejila oru si aago marun-un idaji lo ni awọn agbaṣẹṣe yii yoo fi ṣe e.