Iku Timothy: Adajọ ni ki wọn maa gbe Adedoyin atawọn mẹfa ti wọn fẹsun kan lọ si ọgba ẹwọn Ileṣa

Ọla, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta yii, ni Onidaajọ Adepele Oyebọla-Ojo ti ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo sun ẹjọ Alasẹ ati oludari ileetura Hilton Hotel and Resorts, to wa niluu Ileefẹ, nipinlẹ Ọsun, Dokita Rahman Adedoyin atawọn mẹfa mi-in ti wọn jọ n jẹjọ lori iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke si.

Bẹẹ lo paṣẹ pe ki wọn maa ko wọn lọ si ọgba ẹwọn Ileṣa titi di igba ti igbẹjọ mi-in yoo waye lọla.

Adedoyin atawọn mẹfa mi-in ni wọn fara han nile-ẹjọ naa lori ẹsun koko marun-un ọtọtọ to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ lati paayan, ipaayan, biba ẹri jẹ, fifọwọ kan oku Adegoke ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn mẹfa ti wọn jọ duro niwaju adajọ pẹlu Adedoyin ni Adedeji Adeṣọla,  Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderọgba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem ati Adebayọ Kunle.

Agbẹjọro fun Adedoyin, Ọgbẹni M.K Ẹlẹja (SAN), sọ pe ki kootu fun onibaara oun ni beeli nitori aiya ara rẹ. O ni eyi foju han ninu akọsilẹ ileewosan Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ ati eyi to wa niluu Abuja ti wọn n pe ni Asokoro District Hospital.

Bakan naa ni Ọgbẹni Kunle Adegoke (SAN) to jẹ agbẹjọro fun awọn olujẹjọ yooku beere fun beeli wọn.

O ni ile-ẹjọ ni aṣẹ lati lo agbara wọn lati fun awọn to ba beere fun beeli ni iru anfaani bẹẹ. O ni ki adajọ fun awọn eeyan naa ni beeli, niwọn igba ti ẹni to ṣe oniduuro fun wọn ti kọwọ bọwe pe wọn ko ni i sa lọ lẹyin ti wọn ba gba oniduuro wọn.

Lẹyin gbogbo atotonu naa, Onidaajọ Adepele Oyebọla-Ojo paṣẹ pe ki wọn maa ko awọn afurasi naa lọ si ọgba ẹwọn Ileṣa titi di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọla.

Ṣugbọn bi igbẹjọ naa ṣe pari ni awọn mọlẹbi Adegoke ti wọn pa yii bẹrẹ si i pariwo, ti wọn si n fẹsun kan awọn kan ninu ọrọ wọn pe wọn ti gba owo lori ẹjọ naa. Beẹ ni wọn n ṣepe kikan kikan fun Adedoyin atawọn eeyan rẹ bi wọn ṣe gbe wọn sinu mọto ti wọn n gbe wọn lọ.

Ninu fidio naa ni wọn ti n ṣepe loriṣiiriṣii fun gbogbo ẹni to lọwọ ninu iku ọmọ wọn naa.

Leave a Reply