Iku tun pa aṣofin mi-in l’Ekoo o, Ọnarebu Tunde Buraimọh ti dagbere faye

Faith Adebọla, Eko

A-gbọ-sọgba-nu iṣẹlẹ buruku kan niroyin ọhun, afẹmọjumọ owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, oni ni iku tun pa oju aṣofin ipinlẹ Eko mi-in de, iyẹn Ọnarebu Babatunde Buraimoh.

Titi di bayii, ko ti i sẹni to mọ pato ohun to da ẹmi aṣofin naa legbodo, bo tilẹ jẹ pawọn onimọ iṣegun oyinbo ti n ṣayẹwo lati ṣawari ohun to fa sababi iṣẹlẹ ojiji ọhun.

Aṣofin yii, titi dọjọ iku rẹ, lo n ṣoju agbegbe Kosọfẹ Keji (Kosofe Constituency 2) nipinlẹ Eko, oun si ni alaga igbimọ to n ri si eto iroyin ati aabo nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ pato ohun to pa a, ọrọ tawọn ọgọọrọ eeyan to gbọ nipa iku ojiji naa n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ arun aṣekupani Koronafairọọsi to gbaye kan bayii lo tun ṣọṣẹ.

Ọkan ninu awọn aṣofin to sunmọ oloogbe yii timọtimọ nile igbimọ aṣofin ọhun, Ọnarebu Victor Akande to n ṣoju agbegbe Ọjọ Kin-in-ni, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o sọ fakọroyin wa lori aago pe: ’’Loootọ ni o, mi o ti i le sun lati nnkan bii aago kan oru oni (Furaidee) ti mo ti gbọ nipa ajalu yii. Iyalẹnu nla patapata lo jẹ fun mi, nitori Buraimọh jẹ ọkan lara eeyan ti mo mọ ti ki i fi ọrọ ilera ẹ ṣere rara.’’

‘’O lafinju gan-an, ki i si i fọwọ yẹpẹrẹ mu amọran awọn dokita rẹ tabi tẹnikẹni to ba ti jẹ mọ ti ilera rara, titi dori pipa eewọ arun Korona yii mọ.

‘’Adanu nla leyi jẹ fun wa o. Ọkan pataki to tayọ laarin awọn oloṣelu ni, ko si sigba tọrọ ẹ le kuro lẹnu wa.’’

Ṣugbọn gẹgẹ ba a ṣe gbọ lẹni aṣofin mi-in, iyẹn Ọnarebu Hakeem Ṣokunle to jẹ alaga igbimọ eto ilera nile igbimọ aṣofin Eko, o ni afaimọ ni ko ma jẹ Koronafairọọsi lo mu ẹlẹgbẹ oun yii lọ, afaimọ si ni ko ma jẹ igba ti wọn n ṣe aayan ibanikẹdun fun mọlẹbi Sẹnatọ Ọshinọwọ “Pepperito” ni aṣofin to ku yii ti fara kaaṣa.

Tẹ o ba gbagbe, nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni iku ṣadeede yọwọ aṣofin agba to n ṣoju ẹkun idibo Ila-Oorun Eko yii kan naa nile igbimọ aṣofin agba ilẹ wa, Sẹnetọ Adebayọ Ọshinọwọ, tawọn eeyan mọ si “Pepperito”, lawo, iyẹn lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu to kọja.

 

One thought on “Iku tun pa aṣofin mi-in l’Ekoo o, Ọnarebu Tunde Buraimọh ti dagbere faye

Leave a Reply