Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n ba baale ile kan, Ọgbẹni Philip Ogbodo, daro iku iyawo ẹ, Precious Ogbodo, ẹni ti ina jo pa mọle pẹlu awọn ọmọ wọn mẹrin lalẹ ọjọ kẹẹẹẹdọgbọn, oṣu keji, to kọja yii, nile wọn to wa laduugbo Gyel, Jos, nipinlẹ Plateau.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ẹnikẹni ko ti i le fidi ohun to fa ina naa mulẹ, ṣugbọn awọn to sun mọ wọn sọ pe nnkan eelo ile kan to n lo ina mọnamọna lo fa iku oro fobinrin to n tọ ọmọ ikoko lọwọ naa atawọn ọmọ ẹ mẹta yooku.
Ina ọhun se wọn mọle debii pe wọn ko raaye sa jade, gbogbo ohun to si wa ninu ile naa lo jona raurau pẹlu wọn.
Ọgbẹni Ogbodo to padanu gbogbo idile ẹ yii fi ibanujẹ ọkan ṣalaye pe ko ju wakati kan lọ toun jade nile lati lọọ wo ere bọọlu alafẹsẹgba nibi kan laduugbo, boun ṣe n pada bọ nile loun ri i tawọn eeyan n sare kiri lati pa ina to n jo bulabula jade lati inu ile oun, bẹẹ iyawo atawọn ọmọ oun wa ninu ile naa.
Ẹsẹkẹsẹ ti ina ọhun burẹkẹ ni awọn ọmọ mẹrẹẹrin ti jona mọle, iya wọn nikan ni wọn le gbe dele iwosan, ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Ẹti loun naa si jade laye.
Orukọ awọn ọmọ mẹrin naa ni: Rejoice, Merkel, Harmony ati Angel.