Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn ọrẹ mẹta kan ti wọn jẹ Fulani, Mubarak Bello, Alli Ibrahim ati Fatima Abdullahi, ti wọn yan iṣẹ ijinigbe laayo ni Igbara-Odo Ekiti ni wọn ti wa ni atimọle ọlọpaa niluu Ado-Ekiti bayii, ti won si n sọ tẹnu wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, Ọgbẹni Tunde Mobayọ, ṣalaye pe ni ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni Fulani kan to pe ara rẹ ni Sule Abdullahi pe si ori ẹrọ alagbeeka awọn ọlọpaa, to si fi to wọn leti pe awọn kan ti oun ko mọ ri ti ji ọmọ oun gbe lọ.
O ṣalaye siwaju pe awọn to ji ọmọ naa gbe ti n beere fun ẹgbẹrun lọna aadọta naira ki wọn too le tu ọmọ naa silẹ.
Kọmiṣanna yii fi kun un pe eyi lo fa a ti awọn ọlọpaa kogberegbe ti ẹka RRS ṣe bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa, ti wọn si fi panpẹ ofin mu Mubarak Bello, ẹni ọdun mejilelogun, ni ile ọti kan ni Igbara-Odo, nibi to ti fẹẹ gba ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ti wọn beere gẹgẹ bii owo itusilẹ fun Shekinah.
Ọga ọlọpaa yii ni lẹyin ti wọn fi ọrọ wa Bello lẹnu wo, o ni Alli Ibrahim ni ẹnikeji oun tawọn jọ ji Shekinah gbe, ṣugbọn awọn ti jọwọ rẹ fun Arakunrin kan, Fatima Abdullahi, to si ti gbe e lọ si ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun.
Eyi ni kọmiṣanna lo fa a tawọn ọlọpaa fi lọọ mu Abdullahi niluu Ileṣa, nibi to gbe Shekinah pamọ si.
Ọjọ mẹtala lo ni Shekinah lo lahaamọ awọn ajinigbe naa ki awọn ọlọpaa too ṣawari rẹ, ti wọn si lọọ mu un niluu Ileṣa, nibi ti wọn gbe e pamọ si.
ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ itọpinpin lori ọrọ naa, wọn si fi da awọn mọlẹbi ẹni ti wọn ji gbe yii loju pe awọn mẹta naa ni wọn yoo ko lọ sile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ naa.