Ọrẹlouwa Adedeji
Ayipada ti de ba iwe aṣẹ fun awọn to ba fẹẹ rin irin afẹ tabi ti okoowo lọ si orileede Amẹrika bayii o. Ijọba ilẹ naa ti kede pe dipo ọdun meji ti wọn maa n fun awọn to ba fẹẹ gba fisa lati ṣere lọ si ilu naa, ti wọn si ni anfaani lati lo oṣu mẹrinlelogun (24 months) pẹlu fisa ọlọdun meji ti wọn maa n fun wọn tẹlẹ, ni bayii wọn ti sọ iwe aṣẹ naa di ọlọdun marun-un, ti ẹni to ba ni in lọwọ yoo si ni anfaani lati lo ọgọta oṣu (60 months) lorileede naa.
Ninu ikede ti awọn aṣoju orileede yii nilẹ Naijiria fi sori ikanni wọn ni wọn ti ṣalaye pe lati din bi awọn ọmọ Naijiria to ba fẹẹ lọ si Amẹrika fun igbafẹ ati okoowo ṣe maa n lọọ fi gbogbo igba to si ẹmbasi ku lawọn ṣe fi kun ọdun ti fisa naa le lo lọwọ wọn ki wọn too gba omi-in.
Awọn alaṣẹ naa sọ pe pẹlu bi awọn ṣe fi kun ọdun naa, to ti di ọdun marun-un bayii, awọn ko fi kun owo ti awọn n gba lori gbigba fisa ọhun, eyi to ṣi wa ni ọgọjọ dọla ($160) titi di ba a ṣe n sọ yii.
Lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo bẹrẹ si i jẹ anfaani yii.
Bakan naa ni wọn ni anfaani ti ṣi ṣilẹ fun awọn ti wọn ba kun oju oṣuwọn lati gba fisa ilẹ Amẹrika lai jẹ pe wọn yọju si ẹmbasi wọn rara. Ṣugbọn eyi wa fun awọn ti wọn ba ni gbogbo amuyẹ i eleyii pe fun.
Wọn waa rọ awọn eeyan to ba fẹẹ gba fisa yii pe ki wọn ri i pe ojulowo ikanni awọn ni wọn lọ, ki wọn yago fun ayederu.