Stephen Ajagbe, Ilorin
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, da ẹjọ ti olori ile aṣofin agba tẹlẹ, Dokita Bukọla Saraki, pe ta ko ijọba ipinlẹ Kwara lori bi wọn ṣe wo ile Arugbo.
Pẹlu aṣẹ ile-ẹjọ naa, ijọba ti waa lanfaani lati kọ ohun to ba wu u sori ilẹ naa lai si ẹnikẹni to le da wọn duro.
Adajọ Abiọdun Adewara to fagi le ẹjọ naa ni agbẹjọro awọn Saraki ko le fidi ẹjọ rẹ mulẹ lati fi han pe awọn lo ni ilẹ naa.
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti ẹbi Abubakar Oluṣọla Saraki ti n lo ilẹ naa lati maa fi gbalejo eto oṣelu, ijọba Kwara gba a pada loṣu kejila, ọdun 2019, lati lo o fi kọ ọfiisi awọn oṣiṣẹ.
Ohun tijọba sọ nigba naa ni pe ẹbi Saraki ko gba ilẹ naa lọna to tọ, wọn ko sanwo kankan, bẹẹ si ni ko si iwe kankan tijọba fi gbe ilẹ naa fun wọn, wọn kan lo agbara ti wọn ni lasiko ti wọn wa nipo ijọba lati gba ilẹ naa ni.
Ṣugbọn ẹbi Saraki pẹjọ ta ko igbesẹ tijọba gbe naa nile-ẹjọ. Wọn ni awọn ni ojulowo onilẹ naa.
Nigba tẹjọ naa waye lọjọ Iṣẹgun, ọkan lara awọn agbẹjọro ẹbi Saraki, Ọgbẹni Abdulazeez Ibrahim, sọ fun ile-ẹjọ pe ọga oun to jẹ agbẹjọro agba, Dokita Akin Onigbinde (SAN), ko le yọju sile-ẹjọ nitori pe o n mura eto isinku iya rẹ.
Ṣugbọn agbẹjọro ijọba, Salman Jawondo, ni ọgbọn ati mu ẹjọ naa falẹ lawọn Saraki n da, o ni ko yẹ ki ile-ẹjọ gba wọn laaye lati maa fi akoko rẹ ṣofo, fun idi eyi, ki adajọ fagi le ẹjọ naa.
Adajọ Adewara to gba ẹbẹ agbẹfọba naa wọle ni o ti fi han pe awọn agbẹjọro ẹbi Saraki ko nikan an ṣe, nitori naa, oun da ẹjọ ọhun nu.