Olu-Theo Omolohun Oke-Ogun
Latari bi afurasi ọdaran kan, Abubakar Bello, ṣe ni oun ko jẹbi ẹsun jiji alupupu Bajaj gbe lo mu ki Adajọ agba Majisreeti to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, I. O. Uthman, faaye beeli silẹ fun un, ṣugbọn ti ko ba rowo san, ki wọn da a pada satimọle ọlọpaa titi di akoko ti igbẹjọ yoo fi tun waye.
Ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ti igbẹjọ bẹrẹ lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan Bello, Inpẹkitọ Abiọla Isamọtu to jẹ agbefọba ṣalaye pe ni deede agogo marun-un irọlẹ ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla, to kọja yii, lọwọ tẹ afurasi ọdaran naa pẹlu awọn meji mi-in ti wọn jọ gbimọ-pọ lati ja ọkada Bajaj to ni nọmba BDJ 570 KW gba mọ Ọgbẹni Aliu Isiaka lọwọ.
O ni niṣe lawọn afurasi naa pe ọlọkada yii lori aago pe ko waa gbe awọn lọ si ọja ilu Agọ-Arẹ, wọn sọ ibi tawọn ti maa duro de e fun un. Igba ti ọlọkada naa si de ibẹ, wọn jọọ dunnaa-dura iye owo ti wọn maa san, o si gba lati gbe wọn.
Wọn ni ọlọkada naa pada ṣalaye fawọn ọlọpaa pe bawọn ero ọran yii ṣe fẹẹ gori ọkada naa, ṣadeede ni wọn di igbaju buruku kan ru oun lojiji, koun si too laju lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti lọ ọkada gba mọ oun lọwọ, wọn taari oun danu sẹgbẹẹ igbo, wọn si gbe ọkada naa sa lọ.
Ọkunrin naa ni bii fiimu lọrọ naa jọ, oun o tiẹ mọ ohun toun le ṣe, bẹẹ ni wọn ṣe gbe ọkada naa sa lọ.
Agbefọba ni bawọn ọlọpaa ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn ti bẹrẹ si i fimu finlẹ, ko si pẹ ti ọwọ fi ba afurasi ọdaran yii, tori bi Isiaka ṣe ri i lo ti pariwo pe ọkan lara wọn ni, oun da a mọ daadaa. Ṣugbọn ọwọ ko ti i ba awọn meji to ku, ati ọkada ti wọn gbe lọ naa.
Ẹsun idigunjale, igbimọ-pọ lati ṣiṣẹ ibi ati dida omi alaafia ilu ru ni wọn fi kan afurasi yii, wọn lohun ti wọn ṣe naa lodi si abala kẹrindinlọgọjọ apa kẹta, ati abala irinwo o din mẹwaa iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọyọ.
Afurasi naa loun ko jẹbi, pe oogun ati agunmu amarale loun n ta kaakiri abule ni toun, oun o si mọ nnkan kan nipa ọkada ti wọn jigbe.
Laarin kan ti igbẹjọ naa n lọwọ, olujẹjọ naa bẹrẹ si i ba ogbufọ rẹ, Ọgbẹni Sọliu Lawal, ja, o si bẹrẹ si i ṣe wanranwanran, ṣugbọn agbefọba ni niṣe lo n dibọn lati wa ojuure ile-ẹjọ, o ni ete kile-ẹjọ le ro pe boya nnkan ti ṣe ọpọlọ rẹ lo n da.
Ṣa, Adajọ Uthman ti gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro meji ni iye owo kan naa, o si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹta, oṣu kejila.