Ile-ẹjọ fagi le dida ti wọn da Aṣofin Akinrinbido duro l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Adajọ Ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ, Onidaajọ Ademọla Bọla, ti fagi le dida ti wọn da aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo kin-in-ni, Ọnarebu Leonard Tọmide Akinribido, duro nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Onidaajọ Ademọla ni bi wọn ṣe da ọnarebu yii duro lai ni iye ọjọ ta ko ofin ipinlẹ Ondo, nitori pe ile-igbimọ aṣofin ko lẹtọọ lati da ọmọ ẹgbẹ wọn duro kọja ijokoo kan soso.

Ile-ẹjọ ni ki wọn da ọkunrin naa pada si aaye rẹ lẹyẹ-o-ṣọka, ko si maa ba iṣẹ iriju rẹ lọ gẹgẹ bii aṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ to fi ibo gbe e wọle.

Ọjọ kẹjọ, oṣu keje, ọdun ta a wa yii, nile-igbimọ naa kede pe awọn ti da igbakeji abẹnugan ile, Ọnarebu Irọju Ogundeji, duro. Beẹ lọrọ ọhun kan awọn aṣofin mi-in, Adewale Williams, Favour Tomowewo ati Tọmide Akinribido, lori iwa afojudi ti wọn fẹsun rẹ kan wọn nigba naa.

Ọkọọkan lawọn aṣofin ọhun si lọ sile-ẹjọ lati pẹjọ ta ko iwe gbele-ẹ alailọjọ ti wọn ja fun wọn.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Igbẹjọ Timothy Adegoke: Adedoyin ṣepe fawọn oniroyin ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Iyalẹnu lo jẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii, nigba ti Dokita …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: