Ile-ẹjọ gba Oyetọla laaye lati sayẹwo awọn iwe idibo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lẹyin idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, ti fun oludije labẹ ẹgbẹ APC, Adegboyega Oyetọla, lanfaani lati lo ọna mi-in lati fi fun oludije ẹgbẹ PDP, Ademọla Adeleke, ni iwe ipẹjọ.

 

 

Ọsẹ mẹta sẹyin ni Oyetọla gbe esi idibo naa lọ sile-ẹjọ, o pe ijawe olubori Adeleke nija, o si so ẹgbẹ osẹlu PDP ati ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, mọ awọn olujẹjọ.

 

Lẹyin ti Oyetọla ti gbe awọn iwe ẹsun to ti ni adiju ibo wa lawọn ile idibo ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mọkanla (749) lọ si kootu la gbọ pe Adeleke ko gba iwe ipẹjọ naa, ṣugbọn ajọ INEC ati ẹgbẹ osẹlu PDP ti gba tiwọn.

 

Nigba ti awọn igbimọ kootu naa bẹrẹ ijokoo wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niluu Oṣogbo, wọn fun Oyetọla lanfaani lati ṣayẹwo awọn nnkan ti wọn lo ninu idibo naa, eleyii to wa lakata ajọ INEC.

 

Agbẹjọro fun Oyetọla ati ẹgbẹ oṣelu APC, Yọmi Aliyu (SAN), sọ fun kootu naa, eyi ti Onidaajọ Tertsea Kume jẹ alaga fun, pe ẹni ti ile-ẹjọ fi lẹta ran (bailiff) ko lanfaani lati fun Adeleke ni iwe ipejọ naa latigba to ti n mu un lọ.

 

Aliyu ṣalaye pe ẹni ti beeliifu naa ba lẹnu ọna ile Adeleke niluu Ẹdẹ ko gba iwe ẹsun naa lọjọ ti wọn mu un lọ. O ni yoo tẹ oun lọrun ti ileẹjọ ba le paṣẹ pe ki wọn lẹ iwe ipẹjọ naa mọ patako to wa ni ẹnu ọna yara igbẹjọ.

 

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ibeere mejeeji ti Aliyu beere, Onidaajọ Kume fun Oyetọla lanfaani lati lẹ iwe ipẹjọ Adeleke mọ ẹnu ọna yara igbẹjọ.

Leave a Reply