Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to mọ ibi tọrọ ẹjọ kan ti ẹgbẹ oṣẹlu ‘Allied Peoples Movement’ APM, pe Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ati ẹgbe oṣelu rẹ ti i ṣe, ‘ All Progressive Congress’ APC, niwaju ile-ejọ to n gbọ awọn ẹsun to su yọ lasiko ibo, ‘Presidential Election Petition Court’ (PEPC), to wa niluu Abuja, yoo yọri si.
Agbẹjọro Gideon Ijiagbonya SAN, to n ṣoju ẹgbẹ APM lo pe ẹjọ kan lati ta ko ọna ti Aarẹ Tinubu gba dupo ọhun, eyi to waye lọdun yii. Ṣugbọn agbẹjọro APC, Wole Ọlanipẹkun SAN, ati Charles Edosomwen SAN, ni ki Onidaajọ Haruna Simon Tsammani da ẹjọ ọhun nu patapata, nitori pe ile-ejọ to ga ju lọ nilẹ wa, ‘ Supreme Court’, ti da iru ẹjọ ọhun, eyi ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii nu.
ALAROYE gbọ pe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kefa, ọdun 2023 yii, ni igbẹjọ naa waye. Gbogbo ẹbẹ lọọya Aarẹ Tinubu ati ti ẹgbẹ APC pe ki Onidaajọ Haruna Simon Tsammani da ẹjọ ọhun nu lo ja si pabo, nitoriọkunrin naa ni ko sọrọ ninu ẹbẹ tawọn lọọya mejeeji naa n bẹ rara. O ni bi oun ba da ejọ ọhun nu, bii ẹni pe oun fi ẹtọ awọn olupẹjo naa dun wọn ni.
Adajọ Tsammani ni ohun to yẹ kawọn lọọya Aarẹ Tinubu ati ti ẹgbẹ APC ṣe ni ki wọn maa lọọ gbaradi silẹ lati ta ko gbogbo ẹsun yoowu tawọn olupẹjo naa ba mu wa sile-ẹjọ, bi ẹjọ naa ba ti bẹrẹ ni pẹrẹu ni.
Ṣaaju akoko ọhun ni Gideon to n ṣoju ẹgbẹ APM ti sọ nile-ejọ pe gbogbo bi igbẹjọ ti wọn da nile-ejọ to ga ju lọ nilẹ wa ṣe lọ pata loun ti gbe yẹwo daadaa, toun si ri i pe o ṣee ṣe koun ri idajọ gidi gba lati idi ẹjọ toun ṣẹṣẹ pe yii.
O waa rọ adajọ ile-ejọ naa pe ko foun di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, koun le fi ko gbogbo awọn ẹri toun nilo pata wa si kootu. O ni awọn iwe kọọkan wa to jẹ pe latọdọ ajọ INEC loun maa ti gba wọn, to si ṣee ṣe ko gba oun lakooko diẹ ki wọn too foun.
Loju-ẹsẹ ni Onidaajọ Tsammani ti ta ko aba rẹ naa pe ọjọ to beere fun yẹn ti pọ ju, to si sọ pe oun yoo gbọ ẹjọ rẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu yii.