Ile-ẹjọ maa gba ẹtọ mi pada fun mi lọwọ ijọba awuruju yii-Atiku

Adewale Adeoye

Ondije dupo aarẹ orileede yii lẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ PDP ninu ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, Alhaji Atiku Abubakar ti sọ pe igba diẹ ni olori orileede to wa nipo naa maa lo nipo ọhun, nitori laipẹ ọjọ, ileẹjọ yoo gba ẹtọ oun pada foun lọwọ ẹni to wa nibẹ bayii, toun yoo si di ojulowo aarẹ orileede yii laipẹ.

Atiku sọrọ yii di mimọ lọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹta, osu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lakooko to n ba awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo nipinlẹ Bauchi sọrọ.

Ninu ọrọ rẹ, Atiku ni ko ruju rara pe ọna eru ati magomago ni aarẹ to wa nipo naa fi dori aleefa bayii, oun si nigbagbọ daadaa ninu idajọ awọn adajọ ti ẹjọ oun wa niwaju wọn pe wọn yoo gba ẹtọ oun pada foun laipẹ yii.

O waa rọ awọn aṣofin ọhun, paapaa ju lọ, awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn n lọ sileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja pe ki wọn ṣe ara wọn lọkan ṣoṣo, ki wọn si ma ṣe jẹ kawọn ẹlẹgbẹ wọn yẹpẹrẹ wọn rara. Bakan naa lo gba wọn nimọran pe ki wọn ma ṣe gba gbẹrẹ rara lori ipinnu to le gbe orileede yii de ebute ayọ nigba gbogbo.

Atiku ni, ‘Ẹ n lọọ ṣoju ẹgbẹ wa lọhun-un ni, ẹ ko gbọdọ gba igbakugba laaye rara, ojulowo ọmọ ẹgbẹ alatako ni kẹ ẹ jẹ lọhun-un nigba gbogbo, ọhun ti mo mọ to da mi loju ni pe mo maa too gba ẹtọ mi pada lọwọ ẹni ti wọn fi eru gbe e fun, ileẹjọ ni yoo si gba a fun mi bi akoko ba to gan-an. Ijọba ẹni to wa nipo naa ko lẹsẹ nilẹ rara, oun paapaa si mọ pe ootọ lohun ti mo n sọ’.

 

Leave a Reply