Ile-ẹjọ ni ki ọlọpaa san owo itanran fun Agboọla, igbakeji gomina Ondo tẹlẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Akurẹ ti pasẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede yii lati san ọgọrun-un miliọnu fun igbakeji gomina ana nipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, lori bi wọn ko ṣe fun un laaye lati tete kẹru rẹ kuro nile ijọba.

Onidaajọ F. A. Olubanjọ to gbe idajọ ọhun kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ni ṣe lawọn ẹsọ alaabo tẹ ẹtọ igbakeji gomina tẹlẹ ọhun mọlẹ pẹlu bi wọn ṣe fipa da a duro sile ijọba laarin aago mẹsan-an aarọ ogunjọ, oṣu kẹfa, ọdun 2020.

Adajọ ni iwa tawọn agbofinro ọhun hu ko bojumu rara, nitori pe ti wọn ba le fi iru iya bẹẹ jẹ Agboọla pẹlu gbogbo anfaani ofin asẹmalu to rọ mọ ipo igbakeji gomina to wa nigba naa, ọjọ n bọ ti wọn yoo fipa gbe odidi aarẹ orilẹ-ede lori awawi pe awọn fẹẹ ṣe iwadii rẹ.

Onidaajọ Olubanjọ ni awọn ọlọpaa gbọdọ san ọgọrun-un miliọnu naira fun Agboọla gẹgẹ bii owo ‘gba ma binu’ lori ẹtọ rẹ ti wọn fi du u labẹ ofin dipo biliọnu kan naira ti olupẹjọ n beere fun.

 

Leave a Reply