Ile-ẹjọ ni ki wọn yẹgi fun Tunmiṣe to pa lanledi rẹ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Lẹyin ọdun mẹta to ti pa iya onile rẹ l’Ado-Ekiti, ile-ẹjọ giga kan ti Onidaajọ Oluwatoyin Abọdunde n ṣe akoso rẹ ti paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun ọmọdekunrin kan, Abraham Tunmiṣe, titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.

Tunmiṣe lo lagi mọ ori iya onile rẹ, Bukọla Ọlanrewaju, to jẹ ẹni ọdun marunlelọgọta (65), lori ẹsun pe iya onile yii pe oun ni akalolo ati alainironu ati orukọ miiran ti wọn ko sọ oun.

Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Ọlọrunda, niluu Ado-Ekiti, ninu oṣun Kẹjọ, odun 2019.

Tunmiṣe to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) lo n ṣiṣẹ mọle-mọle ni wọn tun fẹsun kan pe o fipa ba iya onile rẹ yii lo pọ ko too lagi mọ ọn lori, to si sa lọ sile ijọsin kan to wa niluu Akurẹ, nibi ti awọn ọlọpaa ti lọọ mu un.

Ninu awijare rẹ nigba ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ, Tunmiṣe sọ pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, oun fẹẹ gbowo ile oun to ṣẹku pẹlu bi oun ṣe pinnu lati kuro ninu ile naa.

Ṣugbọn iya oloogbe yii di aṣọ oun mun, o si fi eekanna ya oun loju. O ni ni kete toun fi iya onile yii silẹ lo lọọ gbe igi nla kan, to si fẹẹ la a mọ oun lori, ṣugbọn oun gbiyanju lati gba igi naa, ti oun si la a mọ ọn lori, eleyi to pada ja si iku fun.

Tunmiṣe tun ṣalaye pe oun ko fipa ba a lo pọ, oun di ọwọ iya onile yii mu lasan ni.

Ṣugbọn oludari fun ileeṣẹ ijọba to n ri si ẹjọ to jọ mọ lilu ofin ijọba ti ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Julius Ajibare, pe ẹlẹrii mẹrin lati fi idi ẹjọ naa mulẹ.

Nigba to n gbe igbẹjọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Abọdunde sọ pe ki ọdaran naa maa lọ ẹwọn lori ẹsun ifipa ba ni lo pọ ti wọn fi kan an, bakan naa yoo tun paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ lori ẹsun ipaniyan.

Leave a Reply