Ile-ẹjọ sọ Tim satimọle, ọmọ iyawo ẹ lo fipa ba lo pọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Atimọle ọgba ẹwọn to wa ni Kirikiri n’Ikoyi ni baba ẹni ọdun mọkandinlogoji ti wọn porukọ ẹ ni Tim Uwem wa bayii, ile-ẹjọ lo la a mọ keremọnje latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ba ọmọbinrin tiyawo ẹ ti bi fọkọ kan ṣaaju laṣepọ.

Ile-ẹjọ Majisreeti to wa lagbegbe Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko, lo gbọ ẹjọ afurasi ọdaran naa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, awọn ọlọpaa ni wọn wọ baba naa dewaju adajọ lẹyin ti iwadii wọn ti fẹri han pe loootọ niṣẹlẹ naa waye.

Nigba ti agbefọba, Inspẹkitọ Kẹhinde Ọlatunde, n sọrọ lori ẹsun ọhun ni kootu, o ṣalaye pe ile kan to wa ni Ojule kẹwaa, Opopona Ọlaniyi Yusuf, lagbegbe Ikọtun, ni Ọgbẹni Uwem n gbe pẹlu ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogun ti wọn ko fẹẹ darukọ rẹ yii. Yara kan naa si ni gbogbo wọn n sun pẹlu iya ọmọbinrin yii to jẹ iyawo Uwem.

O ni ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, to kọja yii, ni iṣẹlẹ yii waye, iya ọmọbinrin naa ko si nile, ibi ti ọmọbinrin yii sun si lọsan-an ọjọ naa ni wọn ni afurasi ọdaran naa ti ragabu ẹ mọlẹ, to si fipa ba a laṣepọ.

Wọn ni iwa buruku to hu yii lodi si ofin iwa ọdaran ti wọn tun ṣe lọdun 2015 ti ipinlẹ Eko n lo.

Bo tilẹ jẹ pe afurasi naa loun ko jẹbi nigba ti wọn bi i leere, Adajọ O. G. Oghre to gbọ ẹjọ ọhun sọ pe oun ko ti i fẹẹ gbọ alaye Uwem bayii, o ni kawọn ọlọpaa ṣi fi i si ahamọ ọgba ẹwọn naa, titi di ọjọ kẹjidinlogun, oṣu kọkanla, ti igbẹjọ yoo maa tẹ siwaju.

 

Leave a Reply