Ọlọwọ pariwo: Ẹ ma purọ mọ mi o, ko si ounjẹ iranwọ korona laafin mi

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Ọlọwọ tilu Ọwọ, Ọba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye kẹta ti ni irọ patapata lo wa nidii ariwo tawọn eeyan kan n pa kiri pe awọn nnkan iranwọ Covid-19 kan wa ti wọn ko pamọ sinu aafin oun.

Oludamọran agba fun ọba alaye ọhun lori eto iroyin, Sam Adewale, lo sọrọ yii lorukọ kabiyesi ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ọlọwọ ni oun nigbagbọ pe ṣe lawọn to n gbe iru iroyin bẹẹ jade lasiko yii fẹẹ da wahala silẹ, ki wọn si kọ ẹyin oun atawọn eeyan ilu Ọwọ sira awọn.

O ni awọn araalu funra wọn le jẹrii si i pe ọpọlọpọ owo ati ounjẹ loun pin fun wọn lapo ara oun lasiko ofin konilegbele tijọba kede rẹ nitori arun korona.

Ọba Ajibade rọ awọn araalu lati sọra, ki wọn si yago fun ohunkohun to ba le di alaafia ilu Ọwọ lọwọ.

Leave a Reply