Ile ọti ni mo ti pade ọrẹ to kọ mi bi wọn ṣe n ji ọkada gbe – Mojeed

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹdọgbọn kan, Olowookere Mojeed, lọwọ ti tẹ lori ẹsun ole jija niluu Oṣogbo bayii.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu kejila, ọdun yii, lọwọ awọn ọlọpaa tẹ afurasi naa lagbegbe Abija, ni Dada Estate, laago meji ọsan.

Ọkada Bajaj kan to ni nọmba Ọṣun AAW 54 DE lo ji nibẹ, awọn araadugbo si ti fọwọ ba a daadaa ko too di pe awọn ọlọpaa debẹ.

Nigba ti Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, n ṣafihan rẹ nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee,  Mojeed ṣalaye pe ile ọti loun wa lọjọ kan ti oun ti pade ọmọkunrin kan, ti awọn si bẹrẹ si i ṣọrẹ.

O ni nigba tawọn kuro nile ọti naa lo sọ foun nipa oniruuru ọna teeyan le gba ji ọkada gbe tabi ja ọkada gba lọwọ ẹni to ni in.

O fi kun ọrọ rẹ pe igba akọọkọ niyẹn toun yoo huwa naa.

Amọ ṣa, Ọlọkọde ni laipẹ lọmọkunrin naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply